2. Jẹ́ kí adura mi dé ọ̀dọ̀ rẹ;tẹ́tí sí igbe mi.
3. Nítorí pé ọkàn mi kún fún ìyọnu;mo sì súnmọ́ isà òkú.
4. Mo dàbí àwọn tí ó ń wọ ibojì lọ;mo dà bí ẹni tí kò lágbára mọ.
5. N kò yàtọ̀ sí ẹni tí a pa tì sí apá kan láàrin àwọn òkú,mo dàbí ẹni tí a pa, tí ó sùn ninu ibojì,bí àwọn tí ìwọ kò ranti mọ́,nítorí pé wọ́n ti kúrò lábẹ́ ìtọ́jú rẹ.
6. O ti fi mí sinu isà òkú tí ó jìn pupọ,ninu òkùnkùn, àní ninu ọ̀gbun.
7. Ọwọ́ ibinu rẹ wúwo lára mi,ìgbì ìrúnú rẹ sì bò mí mọ́lẹ̀.
8. O ti mú kí àwọn ọ̀rẹ́ kòríkòsùn mi fi mí sílẹ̀;mo sì ti di ẹni ìríra lọ́dọ̀ wọn:mo wà ninu àhámọ́, n kò sì lè jáde;
9. ojú mi ti di bàìbàì nítorí ìbànújẹ́.Lojoojumọ ni mò ń ké pè ọ́, OLUWA;tí mò ń tẹ́wọ́ adura sí ọ.
10. Ṣé òkú ni o óo ṣe iṣẹ́ ìyanu hàn?Ṣé àwọn òkú lè dìde kí wọ́n máa yìn ọ́?
11. Ṣé a lè sọ̀rọ̀ ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ ninu ibojì?Àbí ẹnìkan lè sọ̀rọ̀ òtítọ́ rẹ ninu ìparun?
12. Ṣé a lè rí iṣẹ́ ìyanu rẹ ninu òkùnkùn ikú?Àbí ìrànlọ́wọ́ ìgbàlà rẹ wà ní ilẹ̀ àwọn tí a ti gbàgbé?
13. Ṣugbọn OLUWA, èmi ń ké pè ọ́;ní òwúrọ̀ n óo gbadura sí ọ.