Orin Dafidi 88:14-18 BIBELI MIMỌ (BM)

14. OLUWA, kí ló dé tí o fi ta mí nù?Kí ló dé tí o fi ojú pamọ́ fún mi?

15. Láti ìgbà èwe mi ni a tí ń jẹ mí níyà,tí mo sì fẹ́rẹ̀ kú,mo ti rí ìjẹníyà rẹ tí ó bani lẹ́rù;agara sì ti dá mi.

16. Ìrúnú rẹ bò mí mọ́lẹ̀;ẹ̀rù rẹ sì bà mí dójú ikú.

17. Wọ́n yí mi ká tọ̀sán-tòru bí ìṣàn omi ńlá;wọ́n ká mi mọ́ patapata.

18. O ti mú kí ọ̀rẹ́ kòríkòsùn mi ati àwọn alábàárìn mi kọ̀ mí sílẹ̀;òkùnkùn nìkan ni ó yí mi ká níbi gbogbo.

Orin Dafidi 88