Orin Dafidi 74:6-16 BIBELI MIMỌ (BM)

6. Gbogbo pákó tí a fi dárà sí ara ògirini wọ́n fi àáké ati òòlù fọ́.

7. Wọ́n jó ibi mímọ́ rẹ kanlẹ̀;wọ́n sì ba ilé tí a ti ń pe orúkọ rẹ jẹ́.

8. Wọ́n pinnu lọ́kàn wọn pé, “A óo bá wọn kanlẹ̀ patapata.”Wọ́n dáná sun gbogbo ilé ìsìn Ọlọrun tí ó wà ní ilẹ̀ náà.

9. A kò rí àsíá wa mọ́,kò sí wolii mọ́;kò sì sí ẹnìkan ninu wa tí ó mọ bí ìṣòro wa yóo ti pẹ́ tó.

10. Yóo ti pẹ́ tó, Ọlọrun, tí ọ̀tá yóo máa fi ọ́ ṣẹ̀fẹ̀?Ṣé títí ayé ni ọ̀tá yóo máa gan orúkọ rẹ ni?

11. Kí ló dé tí o ò ṣe nǹkankan?Kí ló dé tí o káwọ́ gbera?

12. Ọlọrun, ìwọ ṣá ni ọba wa láti ìbẹ̀rẹ̀ wá;ìwọ ni o máa ń gbà wá là láàrin gbogbo orílẹ̀-èdè.

13. Ìwọ ni o fi agbára rẹ pín òkun níyà;o fọ́ orí àwọn ẹranko ńlá inú omi.

14. Ìwọ ni o fọ́ orí Lefiatani túútúú;o sì fi òkú rẹ̀ ṣe ìjẹ fún àwọn ẹranko inú aṣálẹ̀.

15. Ìwọ ni o fọ́ àpáta tí omi tú jáde, tí odò sì ń ṣàn,ìwọ ni o sọ odò tí ń ṣàn di ilẹ̀ gbígbẹ.

16. Tìrẹ ni ọ̀sán, tìrẹ náà sì ni òru,ìwọ ni o gbé òṣùpá ati oòrùn ró.

Orin Dafidi 74