1. Ọlọrun, gbé ìlànà òtítọ́ rẹ lé ọba lọ́wọ́;kọ́ ọmọ ọba ní ọ̀nà òdodo rẹ.
2. Kí ó lè máa fi òdodo ṣe ìdájọ́ àwọn eniyan rẹ,kí ó sì máa dá ẹjọ́ àwọn tí ìyà ń jẹ ní ọ̀nà ẹ̀tọ́;
3. kí àwọn eniyan tí ó gbé orí òkè ńlá lè rí alaafia,kí nǹkan sì dára fún àwọn tí ń gbé orí òkè kéékèèké.
4. Jẹ́ kí ó máa gbèjà àwọn eniyan tí ìyà ń jẹ;kí ó máa gba àwọn ọmọ talaka sílẹ̀;kí ó sì rún àwọn aninilára wómúwómú.
5. Ọlọrun, jẹ́ kí àwọn eniyan rẹ máa bẹ̀rù rẹ láti ìran dé ìran,níwọ̀n ìgbà tí oòrùn bá ń ràn, tí òṣùpá sì ń yọ.
6. Jẹ́ kí ọba ó dàbí òjò tí ó rọ̀ sórí koríko tí a ti géàní, bí ọ̀wààrà òjò tí ń rin ilẹ̀.
7. Kí ìwà rere ó gbèrú ní ìgbà tirẹ̀;kí alaafia ó gbilẹ̀ títítí òṣùpá kò fi ní yọ mọ́.
8. Kí ìjọba rẹ̀ ó lọ láti òkun dé òkun,ati láti odò ńlá títí dé òpin ayé.
9. Àwọn tí ń gbé aṣálẹ̀ yóo máa foríbalẹ̀ fún un;àwọn ọ̀tá rẹ̀ yóo sì máa fi ẹnu gbo ilẹ̀ níwájú rẹ̀.
10. Àwọn ọba Taṣiṣi ati àwọn ọba erékùṣù gbogboyóo máa san ìṣákọ́lẹ̀ fún un;àwọn ọba Ṣeba ati ti Seba yóo máa mú ẹ̀bùn wá.
11. Gbogbo àwọn ọba yóo máa wólẹ̀ fún un;gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè yóo sì máa sìn ín.
12. Nítorí pé a máa gba talaka tí ó bá ké pè é sílẹ̀;a sì máa gba àwọn tí ìyà ń jẹ sílẹ̀,ati àwọn tí kò ní olùrànlọ́wọ́.
13. A máa ṣíjú àánú wo àwọn aláìní ati talaka,a sì máa gba àwọn talaka sílẹ̀.
14. A máa gbà wọ́n lọ́wọ́ àwọn aninilára ati oníwà ipá,ẹ̀mí wọn sì ṣe iyebíye ní ojú rẹ̀.
15. Ẹ̀mí rẹ̀ yóo gùn,a óo máa fi wúrà Ṣeba ta á lọ́rẹ,a óo máa gbadura fún un nígbà gbogbo;a óo sì máa súre fún un tọ̀sán-tòru.
16. Ọkà yóo pọ̀ lóko,yóo máa mì lẹ̀gbẹ̀ lórí òkè;èso rẹ̀ yóo dàbí ti Lẹbanoni,eniyan yóo pọ̀ ní ìlú,bíi koríko ninu pápá.