2. Ó fà mí jáde láti inú ọ̀gbun ìparun,láti inú kòtò tí ó kún fún ẹrọ̀fọ̀;ó gbé mi kalẹ̀ lórí àpáta,ó sì fi ẹsẹ̀ mi tẹlẹ̀.
3. Ó fi orin titun sí mi lẹ́nu,àní, orin ìyìn sí Ọlọrun wa.Ọ̀pọ̀ yóo rí i, ẹ̀rù óo bà wọ́n,wọn óo sì gbẹ́kẹ̀lé OLUWA.
4. Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni náà,tí ó gbẹ́kẹ̀ rẹ̀ lé OLUWA,tí kò bá àwọn onigbeeraga rìn,àwọn tí wọn ti ṣìnà lọ sọ́dọ̀ àwọn oriṣa.
5. OLUWA, Ọlọrun mi, o ti ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ìyanu fún wa,o sì ti ro ọ̀pọ̀ èrò rere kàn wá.Kò sí ẹni tí a lè fi wé ọ;bí mo bá ní kí n máa polongo ohun tí o ṣe,kí n máa ròyìn wọn,wọ́n ju ohun tí eniyan lè kà lọ.
6. O ò fẹ́ ẹbọ, bẹ́ẹ̀ ni o ò fẹ́ ọrẹ,ṣugbọn o là mí ní etí;o ò bèèrè ẹbọ sísun tabi ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀.
7. Nígbà náà ni mo wí pé, “Wò ó, mo dé;a ti kọ nípa mi sinu ìwé pé:
8. mo gbádùn láti máa ṣe ìfẹ́ rẹ, Ọlọrun mi;mo sì ń pa òfin rẹ mọ́ ninu ọkàn mi.”
9. Mo ti ròyìn òdodo ninu àwùjọ ńlá.Wò ó, OLUWA n kò pa ẹnu mi mọ́,gẹ́gẹ́ bí o ti mọ̀.
10. Èmi kò fi ìròyìn ìrànlọ́wọ́ ìgbàlà rẹ pamọ́.Mo sọ̀rọ̀ òtítọ́ ati ìgbàlà rẹ;n kò dákẹ́ lẹ́nu nípa òtítọ́ ati ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀,ninu àwùjọ ńlá.
11. Má dáwọ́ àánú rẹ dúró lórí mi, OLUWA,sì jẹ́ kí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ ati òtítọ́ rẹ máa pa mí mọ́.
12. Nítorí pé àìmọye ìdààmú ló yí mi ká,ọwọ́ ẹ̀ṣẹ̀ mi ti tẹ̀ mí,tóbẹ́ẹ̀ tí n kò ríran.Wọ́n pọ̀ ju irun orí mi lọ,ọkàn mi ti dàrú.