Orin Dafidi 31:5-18 BIBELI MIMỌ (BM)

5. Ìwọ ni mo fi ẹ̀mí mi lé lọ́wọ́,o ti rà mí pada, OLUWA, Ọlọrun, olóòótọ́.

6. Mo kórìíra àwọn tí ń bọ oriṣa lásánlàsàn,ṣugbọn OLUWA ni èmi gbẹ́kẹ̀lé.

7. N óo máa yọ̀, inú mi óo sì máa dùn,nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀;nítorí pé o ti rí ìpọ́njú mi,o sì mọ ìṣòro mi.

8. O ò fi mí lé ọ̀tá lọ́wọ́,o sì ti fi ẹsẹ̀ mi lé ilẹ̀ tí ó tẹ́jú.

9. Ṣàánú mi, OLUWA, nítorí pé mo wà ninu ìṣòro.Ìbànújẹ́ sọ ojú mi di bàìbàì;àárẹ̀ sì mú ọkàn ati ara mi.

10. Nítorí pé ìbànújẹ́ ni mo fi ń lo ayé mi;ìmí ẹ̀dùn ni mo sì fi ń lo ọdún kan dé ekeji.Ìpọ́njú ti gba agbára mi;gbogbo egungun mi sì ti di hẹ́gẹhẹ̀gẹ.

11. Ẹni ẹ̀gàn ni mí láàrin gbogbo àwọn ọ̀tá mi,àwòsọkún ni mí fún àwọn aládùúgbò.Mo di àkòtagìrì fún àwọn ojúlùmọ̀ mi,àwọn tí ó rí mi lóde sì ń sá fún mi.

12. Mo di ẹni ìgbàgbé bí ẹni tí ó ti kú;mo dàbí àkúfọ́ ìkòkò.

13. Mò ń gbọ́ tí ọ̀pọ̀ eniyan ń sọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́,bí wọ́n ti ń gbìmọ̀ pọ̀ nípa mi,tí wọ́n sì ń pète ati pa mí;wọ́n ń ṣẹ̀rù bà mí lọ́tùn-ún lósì.

14. Ṣugbọn, mo gbẹ́kẹ̀lé ọ, OLUWA,Mo ní, “Ìwọ ni Ọlọrun mi.”

15. Ìgbà mi ń bẹ ní ọwọ́ rẹ;gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi,ati lọ́wọ́ àwọn tí ń lépa mi.

16. Jẹ́ kí èmi iranṣẹ rẹ rí ojurere rẹ,gbà mí là, nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀.

17. Má jẹ́ kí ojú tì mí, OLUWA,nítorí ìwọ ni mò ń ké pè.Jẹ́ kí ojú ti àwọn eniyan burúkú;jẹ́ kí ẹnu wọn wọ wòwò títí wọ ibojì.

18. Jẹ́ kí àwọn òpùrọ́ yadi,àní àwọn tí ń fi ìgbéraga ati ẹ̀gàn sọ̀rọ̀ àìdára nípa olódodo.

Orin Dafidi 31