1. OLUWA, ìwọ ni mo gbé ojú ẹ̀bẹ̀ sókè sí.
2. Ọlọrun mi, ìwọ ni mo gbẹ́kẹ̀lé,má jẹ́ kí ojú ó tì mí;má jẹ́ kí ọ̀tá ó yọ̀ mí.
3. OLUWA, má jẹ́ kí ojú ó ti ẹnikẹ́ni tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé ọ;àwọn ọ̀dàlẹ̀ eniyan ni kí ojú ó tì.
4. Fi ọ̀nà rẹ hàn mí, OLUWA,kọ́ mi ní ọ̀nà rẹ.
5. Tọ́ mi sí ọ̀nà òtítọ́ rẹ, sì máa kọ́ mi,nítorí ìwọ ni Ọlọrun olùgbàlà mi;ìwọ ni mo gbẹ́kẹ̀lé ní ọjọ́ gbogbo.
6. OLUWA, ranti àánú rẹ, ati ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀,nítorí wọ́n ti wà ọjọ́ ti pẹ́.
7. Má ranti ẹ̀ṣẹ̀ tí mo ti ṣẹ̀ ní ìgbà èwe mi,tabi ibi tí mo ti kọjá ààyè mi;ranti mi, OLUWA, nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀,ati nítorí oore rẹ.
8. Olóore ati olódodo ni OLÚWA,nítorí náà ni ó ṣe ń fi ọ̀nà han àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.
9. A máa tọ́ àwọn onírẹ̀lẹ̀ láti ṣe ohun tí ó tọ́,a sì máa kọ́ wọn ní ìlànà rẹ̀.
10. Gbogbo ọ̀nà OLUWA ni ó kún fún ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ ati òtítọ́,fún àwọn tí ń pa majẹmu ati òfin rẹ̀ mọ́.
11. Nítorí orúkọ rẹ, OLUWA, dárí ẹ̀ṣẹ̀ mi jì mí,nítorí mo jẹ̀bi lọpọlọpọ.
12. Ẹni tí ó bá bẹ̀rù OLUWAni OLUWA yóo kọ́ ní ọ̀nà tí yóo yàn.
13. Irú ẹni bẹ́ẹ̀ yóo ní ọpọlọpọ ọrọ̀,àwọn ọmọ rẹ̀ ni yóo sì jogún ilẹ̀ náà.
14. Àwọn tí ó bá bẹ̀rù OLUWA ni OLUWA ń mú ní ọ̀rẹ́,a sì máa fi majẹmu rẹ̀ hàn wọ́n.
15. OLUWA ni mò ń wò lójú nígbà gbogbo,nítorí òun ni yóo yọ ẹsẹ̀ mi kúrò ninu àwọ̀n.