Orin Dafidi 107:23-30 BIBELI MIMỌ (BM)

23. Àwọn kan wọ ọkọ̀ ojú omi,wọ́n ń ṣòwò lórí agbami òkun,

24. wọ́n rí ìṣe OLUWA,àní iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ ninu ibú.

25. Ó pàṣẹ, ìjì líle sì bẹ̀rẹ̀ sí jà,tóbẹ́ẹ̀ tí ìgbì omi fi ru sókè.

26. Àwọn ọkọ̀ ojú omi fò sókè roro,wọ́n sì tún já wá sílẹ̀ dòò, sinu ibú,jìnnìjìnnì bò wọ́n ninu ewu tí wọ́n wà.

27. Wọ́n ń ta gbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n káàkiri bí ọ̀mùtí,gbogbo ọgbọ́n sì parẹ́ mọ́ wọn ninu.

28. Nígbà náà ni wọ́n ké pe OLUWA ninu ìpọ́njú wọn,ó sì yọ wọ́n ninu ìṣẹ́ wọn.

29. Ó mú kí ìgbì dáwọ́ dúró,ó sì mú kí ríru omi òkun rọlẹ̀ wọ̀ọ̀.

30. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí yọ̀ nígbà tí ilẹ̀ rọ̀,ó sì mú kí wọ́n gúnlẹ̀ sí èbúté ìfẹ́ wọn.

Orin Dafidi 107