Orin Dafidi 107:12-21 BIBELI MIMỌ (BM)

12. Làálàá mú kí agara dá ọkàn wọn,wọ́n ṣubú lulẹ̀ láìsí olùrànlọ́wọ́.

13. Nígbà náà ni wọ́n ké pe OLUWA ninu ìpọ́njú wọn,ó sì gbà wọ́n ninu ìṣẹ́ wọn.

14. Ó yọ wọ́n kúrò ninu òkùnkùn ati ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn,ó sì já ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ wọn.

15. Jẹ́ kí wọn máa yin OLUWA nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀,àní nítorí àwọn iṣẹ́ ìyanu tí ó ṣe fún eniyan.

16. Nítorí pé ó fọ́ ìlẹ̀kùn idẹ,ó sì gé ọ̀pá ìdábùú irin ní àgéjá.

17. Àwọn kan ninu wọn di òmùgọ̀nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn,ojú sì pọ́n wọn nítorí àìdára wọn.

18. Oúnjẹ rùn sí wọn,wọ́n sì súnmọ́ bèbè ikú.

19. Nígbà náà ni wọ́n ké pe OLUWA ninu ìpọ́njú wọn,ó sì yọ wọ́n ninu ìṣẹ́ wọn.

20. Ó sọ̀rọ̀, ó sì mú wọn lára dá,ó tún kó wọn yọ ninu ìparun.

21. Jẹ́ kí wọn máa yin OLUWA nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀,àní, nítorí àwọn iṣẹ́ ìyanu tí ó ṣe fún eniyan.

Orin Dafidi 107