Orin Dafidi 105:1-15 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ OLUWA, ẹ pe orúkọ rẹ̀,ẹ fi iṣẹ́ rẹ̀ hàn ní gbogbo orílẹ̀-èdè.

2. Ẹ kọrin sí i, ẹ kọ orin ìyìn sí i,ẹ sọ nípa gbogbo iṣẹ́ ribiribi rẹ̀.

3. Ẹ máa fi orúkọ mímọ́ rẹ̀ yangàn,kí ọkàn àwọn tí ń wá OLUWA ó máa yọ̀.

4. Ẹ wá ojurere OLUWA ati agbára rẹ̀,ẹ máa wá ojurere rẹ̀ nígbà gbogbo.

5. Ẹ ranti iṣẹ́ ribiribi tí ó ti ṣe,ẹ ranti iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ ati ìdájọ́ rẹ̀.

6. Ẹ̀yin ọmọ Abrahamu, iranṣẹ rẹ̀,ẹ̀yin ọmọ Jakọbu, àyànfẹ́ rẹ̀.

7. OLUWA ni Ọlọrun wa,ìdájọ́ rẹ̀ kárí gbogbo ayé.

8. Títí lae ni ó ń ranti majẹmu rẹ̀,ó ranti àṣẹ tí ó pa fún ẹgbẹẹgbẹrun ìran,

9. majẹmu tí ó bá Abrahamu dá,ìlérí tí ó fi ìbúra ṣe fún Isaaki,

10. tí ó fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ fún Jakọbu gẹ́gẹ́ bí òfin,àní fún Israẹli gẹ́gẹ́ bíi majẹmu ayérayé,

11. ó ní: “Ẹ̀yin ni n óo fi ilẹ̀ Kenaani fún,yóo jẹ́ ìpín yín tí ẹ óo jogún.”

12. Nígbà tí wọ́n kéré ní iye,tí wọn kò tíì pọ̀ rárá, tí wọn sì jẹ́ àjèjì ní ilẹ̀ náà,

13. tí wọn ń káàkiri láti orílẹ̀-èdè dé orílẹ̀-èdè,láti ìjọba kan dé òmíràn,

14. kò jẹ́ kí ẹnikẹ́ni ni wọ́n lára,ó bá àwọn ọba wí nítorí wọn.

15. Ó ní, “Ẹ kò gbọdọ̀ fọwọ́ kan ẹni àmìòróró mi,ẹ kò sì gbọdọ̀ ṣe àwọn wolii mi níbi.”

Orin Dafidi 105