Orin Dafidi 104:6-13 BIBELI MIMỌ (BM)

6. O fi ibú omi bò ó bí aṣọ,omi sì borí àwọn òkè ńlá.

7. Nígbà tí o bá wọn wí, wọ́n sá,nígbà tí o sán ààrá, wọ́n sá sẹ́yìn.

8. Wọ́n ṣàn kọjá lórí òkèlọ sí inú àfonífojì,sí ibi tí o yàn fún wọn.

9. O ti pa ààlà tí wọn kò gbọdọ̀ kọjá,kí wọn má baà tún bo ayé mọ́lẹ̀ mọ́.

10. Ìwọ ni o mú kí àwọn orísun máa tú omi jáde ní àfonífojì;omi wọn sì ń ṣàn láàrin àwọn òkè.

11. Ninu omi wọn ni gbogbo ẹranko tí ń mu,ibẹ̀ sì ni àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó tí ń rẹ òùngbẹ.

12. Lẹ́bàá orísun wọnyini àwọn ẹyẹ ń gbé,wọ́n sì ń kọrin lórí igi.

13. Láti ibùgbé rẹ lókè ni o tí ń bomi rin àwọn òkè ńlá.Ilẹ̀ sì mu àmutẹ́rùn nípa iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.

Orin Dafidi 104