21. Àwọn ẹgbọ̀rọ̀ kinniun ń bú fún ìjẹ,wọ́n ń wo ojú Ọlọrun fún oúnjẹ.
22. Nígbà tí oòrùn bá là, wọn á wọ́ lọ;wọn á lọ dùbúlẹ̀ sinu ihò wọn.
23. Ọmọ eniyan á sì jáde lọ síbi iṣẹ́ rẹ̀,á lọ síbi làálàá rẹ̀ títí di àṣáálẹ́.
24. OLUWA, ìyanu ni iṣẹ́ ọwọ́ rẹ!Ọgbọ́n ni o fi dá gbogbo wọn.Ayé kún fún àwọn ẹ̀dá rẹ.
25. Ẹ wo òkun bí ó ti tóbi tí ó sì fẹ̀,ó kún fún ọ̀kẹ́ àìmọye ẹ̀dá,nǹkan abẹ̀mí kéékèèké ati ńláńlá.
26. Ibẹ̀ ni ọkọ̀ ojú omi ń gbà lọ,ati Lefiatani tí o dá láti máa ṣeré ninu òkun.
27. Ojú rẹ ni gbogbo wọn ń wò,fún ìpèsè oúnjẹ ní àkókò.
28. Nígbà tí o bá fún wọn, wọn á kó o jọ,nígbà tí o bá la ọwọ́,wọn á jẹ ohun dáradára ní àjẹyó.