Nọmba 23:11-25 BIBELI MIMỌ (BM)

11. Nígbà náà ni Balaki sọ fún Balaamu pé, “Kí ni ò ń ṣe sí mi yìí? Mo mú ọ wá láti ṣépè lé àwọn ọ̀tá mi, ṣugbọn ò ń súre fún wọn.”

12. Ó sì dáhùn pé, “Ohun tí OLUWA bá sọ fún mi ni mo gbọdọ̀ sọ.”

13. Balaki sọ fún Balaamu pé, “Jẹ́ kí á lọ sí ibòmíràn tí o ti lè rí wọn. Apákan wọn ni o óo rí, o kò ní rí gbogbo wọn, níbẹ̀ ni o óo ti bá mi ṣépè lé wọn.”

14. Ó bá mú un lọ sórí òkè Pisiga ní pápá Sofimu. Ó tún tẹ́ pẹpẹ meje, ó sì fi akọ mààlúù kọ̀ọ̀kan ati àgbò kọ̀ọ̀kan rúbọ lórí pẹpẹ kọ̀ọ̀kan.

15. Balaamu sọ fún Balaki pé, “Dúró ti ẹbọ sísun rẹ, n óo lọ pàdé OLUWA lọ́hùn-ún.”

16. OLUWA rán Balaamu pada sí Balaki pẹlu ohun tí yóo sọ.

17. Nígbà tí ó pada dé ó bá Balaki ati àwọn àgbààgbà Moabu, wọ́n dúró ti ẹbọ sísun náà, Balaki sì bèèrè ohun tí OLUWA sọ lọ́wọ́ rẹ̀.

18. Balaamu bá bẹ̀rẹ̀ sí fi òwe sọ̀rọ̀, ó ní:“Balaki, dìde, wá gbọ́,fetí sí mi, ọmọ Sipori;

19. Ọlọrun kò jọ eniyan tí máa ń purọ́,bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe eniyan tí máa ń yí ọkàn pada.Ohun tí ó bá ti sọ ni yóo ṣe,bí ó bá sì sọ̀rọ̀ yóo rí bẹ́ẹ̀.

20. OLUWA ti sọ fún mi pé kí n bukun wọn,Ọlọrun pàápàá ti bukun wọn, èmi kò lè mú ibukun náà kúrò.

21. Kò rí ìparun ninu Jakọbu,bẹ́ẹ̀ ni kò rí ìpọ́njú níwájú Israẹli.OLUWA Ọlọrun wọn wà pẹlu wọn,Òun sì ni ọba wọn.

22. OLUWA mú wọn jáde láti Ijipti wá,Ó sì ń jà fún wọn bí àgbáǹréré.

23. Kò sí òògùn kan tí ó lè ran Jakọbu,bẹ́ẹ̀ ni àfọ̀ṣẹ kan kò lè ran Israẹli.Wò ó! Àwọn eniyan yóo máa wí nípa Israẹli pé,‘Wo ohun tí Ọlọrun ṣe!’

24. Wo orílẹ̀-èdè Israẹli! Ó dìde dúró bí abo kinniun,ó sì gbé ara rẹ̀ sókè bíi kinniun.Kò ní sinmi títí yóo fi jẹ ẹran tí ó pa tán,tí yóo sì fi mu ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ tán.”

25. Balaki sì sọ fún Balaamu pé, “Níwọ̀n ìgbà tí o ti kọ̀, tí o kò ṣépè lé wọ́n, má súre fún wọn.”

Nọmba 23