Nọmba 21:2-13 BIBELI MIMỌ (BM)

2. Nígbà náà ni àwọn ọmọ Israẹli bá OLUWA jẹ́jẹ̀ẹ́ pé, Bí ó bá ti àwọn lẹ́yìn tí àwọn bá ṣẹgun àwọn eniyan náà, àwọn óo pa àwọn eniyan náà run patapata.

3. OLUWA gbọ́ ohùn àwọn ọmọ Israẹli, ó sì ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ṣẹgun àwọn ará Kenaani. Wọ́n run àwọn ati àwọn ìlú wọn patapata. Àwọn ọmọ Israẹli sì sọ ibẹ̀ ní Horima.

4. Àwọn ọmọ Israẹli gbéra láti òkè Hori, wọ́n gba ọ̀nà Òkun Pupa, láti yípo lọ lẹ́yìn ilẹ̀ Edomu. Ṣugbọn sùúrù tán àwọn eniyan náà lójú ọ̀nà,

5. wọ́n sì sọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọrun ati Mose, wọ́n ní, “Kí ló dé tí ẹ fi kó wa wá láti Ijipti, pé kí á wá kú ninu aṣálẹ̀ yìí? Kò sí oúnjẹ, kò sí omi, burẹdi fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ yìí ti sú wa.”

6. OLUWA bá rán ọpọlọpọ ejò amúbíiná sí àwọn eniyan náà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí bù wọ́n jẹ, ọpọlọpọ ninu wọn sì kú.

7. Wọ́n bá wá sọ́dọ̀ Mose, wọ́n ní, “A ti ṣẹ̀ nítorí tí a ti sọ̀rọ̀ òdì sí OLUWA ati sí ọ. Gbadura sí OLUWA kí ó mú ejò wọnyi kúrò lọ́dọ̀ wa.” Mose bá gbadura fún àwọn eniyan náà.

8. OLUWA sọ fún Mose pé, “Fi idẹ rọ ejò amúbíiná kan, kí o gbé e kọ́ sórí ọ̀pá gígùn kan, ẹnikẹ́ni tí ejò bá bù jẹ, tí ó bá wo ejò idẹ náà yóo yè.”

9. Mose bá rọ ejò idẹ kan, ó gbé e kọ́ sórí ọ̀pá gígùn kan, ẹnikẹ́ni tí ejò bá bù jẹ, tí ó bá ti wò ó, a sì yè.

10. Àwọn ọmọ Israẹli ṣí kúrò níbẹ̀, wọ́n pa àgọ́ wọn sí Obotu.

11. Lẹ́yìn tí wọ́n kúrò ní Obotu wọ́n pa àgọ́ sí Òkè-Abarimu ní aṣálẹ̀ tí ó wà níwájú Moabu, ní ìhà ìlà oòrùn.

12. Wọ́n gbéra láti ibẹ̀, wọ́n lọ pa àgọ́ sí àfonífojì Seredi.

13. Wọ́n tún ṣí kúrò ní àfonífojì Seredi, wọ́n pa àgọ́ wọn sí òdìkejì odò Arinoni, tí ó wà ní aṣálẹ̀ tí ó bẹ̀rẹ̀ láti agbègbè àwọn ará Amori. Odò Arinoni jẹ́ ààlà ilẹ̀ Moabu, ó wà láàrin ilẹ̀ Moabu ati ilẹ̀ Amori.

Nọmba 21