10. o sì ṣe iṣẹ́ àmì ati ìyanu, o fi jẹ Farao níyà ati gbogbo àwọn iranṣẹ rẹ̀ ati gbogbo àwọn ará ilẹ̀ náà, nítorí pé wọ́n hùwà ìgbéraga sí àwọn baba wa, o gbé orúkọ ara rẹ ga gẹ́gẹ́ bí ó ti wà lónìí.
11. O pín òkun sí meji níwájú wọn, kí wọ́n lè gba ààrin rẹ̀ kọjá lórí ilẹ̀ gbígbẹ, o sì sọ àwọn tí wọn ń lé wọn lọ sinu ibú bí ẹni sọ òkúta sinu omi.
12. Ò ń fi ọ̀wọ̀n ìkùukùu darí wọn lọ́sàn-án, o sì ń fi ọ̀wọ̀n iná darí wọn lóru, ò ń tọ́ wọn sí ọ̀nà tí ó yẹ kí wọ́n rìn.
13. O sọ̀kalẹ̀ sí orí òkè Sinai, o bá wọn sọ̀rọ̀ láti ọ̀run, o sì fún wọn ní ìlànà ati ìdájọ́ tí ó tọ̀nà ati àwọn òfin tòótọ́,
14. O kọ́ wọn láti máa pa ọjọ́ ìsinmi rẹ mọ́, o sì tún pèsè ẹ̀kọ́, ìlànà, ati òfin fún wọn láti ọwọ́ Mose iranṣẹ rẹ.
15. O fún wọn ní oúnjẹ láti ọ̀run wá nígbà tí ebi ń pa wọ́n, o sì ń fún wọn ní omi mu láti inú àpáta nígbà tí òùngbẹ ń gbẹ wọ́n. O ní kí wọ́n lọ gba ilẹ̀ tí o ti ṣèlérí láti fún wọn bí ohun ìní wọn.
16. “Àwọn ati àwọn baba wa hùwà ìgbéraga, wọn ṣe orí kunkun, wọn kò sì pa òfin náà mọ́.
17. Wọ́n kọ̀ wọn kò gbọ́ràn, wọn kò sì ranti àwọn ohun ìyanu tí o ṣe láàrin wọn, ṣugbọn wọ́n ṣoríkunkun, wọ́n sì yan olórí láti kó wọn pada sinu ìgbèkùn wọn ní Ijipti. Ṣugbọn Ọlọrun tíí dáríjì ni ni Ọ́, olóore ọ̀fẹ́ ati aláàánú sì ni ọ́, o kì í tètè bínú, o sì kún fún ìfẹ́ tí kìí yẹ̀, nítorí náà o kò kọ̀ wọ́n sílẹ̀.
18. Nígbà tí wọ́n tilẹ̀ yá ère ọmọ mààlúù, tí wọn ń sọ pé, ‘Ọlọrun wọn tí ó kó wọn kúrò ní ilẹ̀ Ijipti ni,’ tí wọ́n sì ń hu ìwà ìmúnibínú,
19. nítorí àánú rẹ, o kò kọ̀ wọ́n sílẹ̀ sinu aṣálẹ̀. Ọ̀wọ̀n ìkùukùu tí ó ń tọ́ wọn sọ́nà kò fìgbà kan kúrò lọ́dọ̀ wọn lọ́sàn-án, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀wọ̀n iná kò sì fi wọ́n sílẹ̀ lóru. Ó ń tan ìmọ́lẹ̀ fún wọn lálẹ́, láti máa tọ́ wọn sí ọ̀nà tí wọn yóo máa rìn.
20. O fún wọn ní ẹ̀mí rere rẹ láti máa kọ́ wọn, o kò dá mana rẹ dúró, o fi ń bọ́ wọn. O sì ń fún wọn ni omi mu nígbà tí òùngbẹ bá ń gbẹ wọ́n.
21. Ogoji ọdún ni o fi bọ́ wọn ninu aṣálẹ̀, wọn kò sì ṣe àìní ohunkohun, aṣọ wọn kò gbó, ẹsẹ̀ wọn kò sì wú.
22. O gba ọpọlọpọ ìjọba ati ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè fún wọn, o sì fi ibi gbogbo fún wọn. Wọ́n gba ilẹ̀ ìní Sihoni, ọba Heṣiboni, ati ti Ogu, ọba Baṣani.
23. O jẹ́ kí ìrandíran wọn pọ̀ sí i bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run, o sì kó wọn dé ilẹ̀ tí o ti ṣèlérí fún àwọn baba wọn pé wọn yóo lọ gbà.
24. Àwọn ọmọ wọn lọ sí ilẹ̀ náà, wọ́n sì gbà á, o ṣẹgun àwọn ará Kenaani tí wọn ń gbé orí ilẹ̀ náà tẹ́lẹ̀, o sì fi wọ́n lé àwọn ọmọ Israẹli lọ́wọ́, àtàwọn, àtọba wọn, àtilẹ̀ wọn, kí àwọn ọmọ Israẹli lè ṣe wọ́n bí wọ́n bá ti fẹ́.