5. Ẹ óo máa pa ọkà títí tí èso àjàrà yóo fi tó ká, ẹ óo sì máa ká èso àjàrà lọ́wọ́, títí àwọn nǹkan oko yóo fi tó gbìn. Ẹ óo jẹ, ẹ óo yó, ẹ óo sì máa gbé inú ilẹ̀ yín láìléwu.
6. “N óo fun yín ní alaafia ní ilẹ̀ náà, ẹ óo dùbúlẹ̀, kò sí ẹnìkan tí yóo sì dẹ́rùbà yín. N óo lé àwọn ẹranko burúkú kúrò ní ilẹ̀ náà, ogun kò sì ní jà ní ilẹ̀ náà.
7. Ẹ óo lé àwọn ọ̀tá yín jáde, ẹ óo sì máa fi idà pa wọ́n.
8. Marun-un ninu yín yóo lé ọgọrun-un ọ̀tá sẹ́yìn, ọgọrun-un ninu yín yóo sì lé ẹgbaarun (10,000) àwọn ọ̀tá yín sẹ́yìn, idà ni ẹ óo fi máa pa wọ́n.
9. N óo fi ojurere wò yín, n óo mú kí ẹ máa bímọlémọ, kí ẹ sì pọ̀ sí i, n óo sì fi ìdí majẹmu mi múlẹ̀ pẹlu yín.
10. Ẹ óo jẹ àwọn nǹkan oko tí ẹ kó sí inú abà fún ọjọ́ pípẹ́, ẹ óo sì máa ru ìyókù wọn dànù kí ẹ lè rí ààyè kó tuntun sí.
11. N óo fi ààrin yín ṣe ibùgbé mi, ọkàn mi kò sì ní kórìíra yín.
12. N óo máa rìn láàrin yín, n óo jẹ́ Ọlọrun yín, ẹ óo sì jẹ́ eniyan mi.
13. Èmi ni OLUWA Ọlọrun yín, tí ó ko yín jáde wá láti ilẹ̀ Ijipti, kí ẹ má baà ṣe ẹrú wọn mọ́. Mo ti dá igi ìdè àjàgà yín kí ẹ lè máa rìn lóòró gangan.
14. “Ṣugbọn tí ẹ bá kọ̀, tí ẹ kò gbọ́ tèmi, tí ẹ kò sì pa gbogbo àwọn òfin mi mọ́,
15. bí ẹ bá Pẹ̀gàn àwọn ìlànà mi, tí ọkàn yín sì kórìíra ìdájọ́ mi, tóbẹ́ẹ̀ tí ẹ kọ̀ láti pa àwọn òfin mi mọ́, tí ẹ̀ ń ba majẹmu mi jẹ́,
16. ohun tí n óo ṣe sí yín nìyí: n óo rán ìbẹ̀rù si yín lójijì, àìsàn burúkú ati ibà tí ń bani lójú jẹ́ yóo bẹ́ sílẹ̀ láàrin yín, ẹ óo sì bẹ̀rẹ̀ sí kú sára. Bí ẹ bá gbin ohun ọ̀gbìn, òfò ni yóo jásí, nítorí pé àwọn ọ̀tá yín ni yóo jẹ ẹ́.
17. N óo kẹ̀yìn sí yín, àwọn ọ̀tá yín yóo sì ṣẹgun yín. Àwọn tí ẹ kórìíra ni yóo máa jọba lórí yín, ẹ óo sì máa sá nígbà tí ẹnikẹ́ni kò le yín.
18. “Bí mo bá ṣe gbogbo èyí, sibẹ tí ẹ kò gbọ́ tèmi, n óo jẹ yín níyà ní ìlọ́po meje, fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín.
19. Pẹlu gbogbo agbára tí ẹ ní, n óo tẹ̀ yín lórí ba; òjò yóo kọ̀, kò ní rọ̀, ilẹ̀ yóo sì le bí àpáta.
20. Iṣẹ́ àṣedànù ni ẹ óo máa ṣe, nítorí pé, ilẹ̀ kò ní mú ìbísí rẹ̀ wá, àwọn igi oko kò ní so.
21. “Bí ẹ bá lòdì sí mi, tí ẹ kò sì gbọ́ tèmi, n óo jẹ yín níyà ní ìlọ́po meje, fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín.
22. N óo da àwọn ẹranko burúkú sáàrin yín, tí yóo máa gbé yín lọ́mọ lọ, wọn yóo run àwọn ẹran ọ̀sìn yín, n óo dín yín kù, tí yóo fi jẹ́ pé ilẹ̀ yín yóo di ahoro.
23. “Lẹ́yìn gbogbo èyí, bí ẹ ba kọ̀, ti ẹ kò yipada, ṣugbọn tí ẹ kẹ̀yìn sí mi,
24. èmi gan-an yóo wá kẹ̀yìn si yín, n óo sì jẹ yín níyà ní ìlọ́po meje, fún ẹ̀ṣẹ̀ yín.
25. N óo fi ogun ko yín, tí yóo gbẹ̀san nítorí majẹmu mi. Bí ẹ bá sì kó ara yín jọ sinu àwọn ìlú olódi yín, n óo rán àjàkálẹ̀ àrùn sí ààrin yín, n óo sì fi yín lé àwọn ọ̀tá yín lọ́wọ́.