Kronika Keji 18:20-29 BIBELI MIMỌ (BM)

20. Nígbà náà ni ẹ̀mí kan jáde, ó sì dúró níwájú OLUWA, ó ní, ‘N óo lọ tan Ahabu jẹ.’ OLUWA bá bèèrè pé, ‘Ọgbọ́n wo ni o fẹ́ dá?’

21. Ẹ̀mí náà dáhùn pé, ‘N óo lọ sọ gbogbo àwọn wolii Ahabu di wolii èké.’ OLUWA bá dá a lóhùn pé, ‘Ìwọ ni kí o lọ tàn án jẹ, o óo sì ṣe àṣeyọrí, lọ ṣe bí o ti wí.’ ”

22. Mikaya ní, “OLUWA ni ó mú kí àwọn wolii rẹ wọnyi máa sọ àsọtẹ́lẹ̀ èké, ṣugbọn àjálù burúkú ni OLUWA ti pinnu pé yóo dé bá ọ.”

23. Nígbà náà ni Sedekaya, ọmọ Kenaana súnmọ́ Mikaya, ó gbá a létí, ó wí pé, “Nígbà wo ni ẹ̀mí OLUWA fi mí sílẹ̀ tí ó wá ń bá ọ sọ̀rọ̀?”

24. Mikaya dáhùn pé, “Ojú rẹ yóo já a ní ọjọ́ náà, nígbà tí o bá lọ sá pamọ́ sí kọ̀rọ̀ yàrá.”

25. Nígbà náà ni Ahabu ọba pàṣẹ pé kí wọ́n mú Mikaya lọ sọ́dọ̀ Amoni, gomina ìlú ati sọ́dọ̀ Joaṣi, ọmọ ọba, kí wọ́n sì sọ fún wọn pé:

26. Ẹ ju ọkunrin yìí sẹ́wọ̀n, kí wọ́n sì máa fún un ní omi ati burẹdi nìkan títí òun óo fi pada dé ní alaafia.

27. Mikaya dáhùn pé, “Tí o bá pada dé ní alaafia, a jẹ́ pé kì í ṣe OLUWA ni ó gba ẹnu mi sọ̀rọ̀.” Ó sì tún sọ siwaju sí i pé, kí olukuluku fetí sí ohun tí òun wí dáradára.

28. Ahabu ọba Israẹli ati Jehoṣafati ọba Juda lọ gbógun ti Ramoti Gileadi.

29. Ahabu sọ fún Jehoṣafati pé, “Bí a ti ń lọ sógun yìí, n óo yí ara pada. Ṣugbọn ìwọ ní tìrẹ, wọ aṣọ ìgúnwà rẹ.” Ọba Israẹli bá yíra pada, ó lọ sí ojú ogun.

Kronika Keji 18