9. Nítorí ẹ mọ oore-ọ̀fẹ́ Oluwa wa Jesu Kristi, pé nítorí tiwa, òun tí ó jẹ́ ọlọ́rọ̀ di aláìní, kí ẹ lè di ọlọ́rọ̀ nípa àìní tirẹ̀.
10. Èrò mi lórí ọ̀rọ̀ yìí ni pé ohun tí ó dára jùlọ fun yín ni. Nígbà tí kì í tíí ṣe pé ẹ ti ń ṣe é nìkan ni, ṣugbọn tìfẹ́tìfẹ́ ni ẹ ti fi ń ṣe é láti ọdún tí ó kọjá,
11. ó tó àkókò wàyí, ẹ ṣe é parí. Irú ìtara tí ẹ fẹ́ fi ṣe é ni kí ẹ fi parí rẹ̀. Kí ẹ ṣe é gẹ́gẹ́ bí ẹ ti ní tó.
12. Bí ìfẹ́ láti mú ọrẹ wá bá wà, Ọlọrun gba ohun tí eniyan bá mú wá. Ọlọrun kò bèèrè ohun tí eniyan kò ní.
15. Gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ní àkọsílẹ̀, “Ẹni tí ó kó ọ̀pọ̀ kò ní jù, ẹni tí ó kó díẹ̀ kò ṣe aláìní tó.”
16. Ọpẹ́ ni fún Ọlọrun tí ó fi irú ìtara kan náà tí mo ní sí ọkàn Titu.
17. Nítorí nígbà tí a sọ pé kí ó wá sọ́dọ̀ yín, pẹlu ayọ̀ ni ó fi gbà láti wá. Òun fúnrarẹ̀ tilẹ̀ ní àníyàn láti wá sọ́dọ̀ yín tẹ́lẹ̀.
18. A rán arakunrin tí ó lókìkí ninu gbogbo àwọn ìjọ nítorí iṣẹ́ rẹ̀ nípa ìyìn rere pé kí ó bá a wá.
19. Kì í ṣe pé ó lókìkí nìkan ni, ṣugbọn òun ni ẹni tí gbogbo àwọn ìjọ yàn pé kí ó máa bá wa kiri nípa iṣẹ́ oore-ọ̀fẹ́ tí à ń ṣe fún ògo Oluwa ati láti fi ìtara wa hàn.
20. À ń ṣe èyí kí ẹnikẹ́ni má baà rí nǹkan wí sí wa nípa ọ̀nà tí à ń gbà ṣe ètò ti ẹ̀bùn yìí.