9. Ọ̀nà tí Ọlọrun fi fi ìfẹ́ tí ó ní sí wa hàn ni pé ó ti rán ààyò ọmọ rẹ̀ wá sáyé kí á lè ní ìgbàlà nípasẹ̀ rẹ̀.
10. Ọ̀nà tí a fi mọ ìfẹ́ nìyí: kì í ṣe pé àwa ni a fẹ́ràn Ọlọrun ṣugbọn òun ni ó fẹ́ràn wa, tí ó rán ọmọ rẹ̀ wá sáyé láti jẹ́ ọ̀nà ìwẹ̀mọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wa.
11. Olùfẹ́, bí Ọlọrun bá fẹ́ràn wa tó báyìí, ó yẹ kí àwa náà fẹ́ràn ọmọnikeji wa.
12. Ẹnikẹ́ni kò rí Ọlọrun rí, bí a bá fẹ́ràn ọmọnikeji wa, Ọlọrun ń gbé inú wa, ìfẹ́ rẹ̀ sì ti di pípé ninu wa.
13. A mọ̀ pé à ń gbé inú Ọlọrun ati pé òun náà ń gbé inú wa nítorí pé ó fún wa ní ẹ̀mí rẹ̀.
14. Àwa ti rí i, a sì ń jẹ́rìí pé Baba ti rán Ọmọ rẹ̀ láti jẹ́ olùgbàlà aráyé.
15. Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́wọ́ pé Ọmọ Ọlọrun ni Jesu, Ọlọrun ń gbé inú rẹ̀, òun náà sì ń gbé inú Ọlọrun.