1. Ẹ fun fèrè ní Sioni,ẹ kéde ìdágìrì lórí òkè mímọ́ mi.Kí gbogbo àwọn tí wọn ń gbé ilẹ̀ náà wárìrì,nítorí ọjọ́ OLUWA ń bọ̀, ó sì ti dé tán.
2. Yóo jẹ́ ọjọ́ òkùnkùn ati ìbànújẹ́,ọjọ́ ìkùukùu ati òkùnkùn biribiri.Àwọn ọmọ ogun yóo bo gbogbo òkè ńlá,bí ìgbà tí òkùnkùn bá ń ṣú bọ̀.Irú rẹ̀ kò ṣẹlẹ̀ rí ní ìgbà àtijọ́,bẹ́ẹ̀ ni irú rẹ̀ kò sì tún ní ṣẹlẹ̀ mọ́ títí lae.
3. Iná ń jó àjórun níwájú wọn,ahọ́n iná ń yọ lálá lẹ́yìn wọn.Ilẹ̀ náà dàbí ọgbà Edẹni níwájú wọn,ṣugbọn lẹ́yìn wọn, ó dàbí aṣálẹ̀ tí ó ti di ahoro,kò sì sí ohun tí yóo bọ́ lọ́wọ́ wọn.
4. Ìrísí wọn dàbí ìrísí ẹṣin,wọ́n sì ń sáré bí ẹṣin tí ń lọ ojú ogun.
5. Ìró wọn dàbí ìró kẹ̀kẹ́ ogun,wọ́n ń bẹ́ lórí àwọn òkè ńlá.Ìró wọn dàbí ìró iná tí ń jó pápá,bí ìgbà tí àwọn alágbára ọmọ ogun múra fún ogun.
6. Ìdààmú bá àwọn orílẹ̀-èdè tí ó bá ti fojú kàn wọ́n,gbogbo ọkàn á rẹ̀wẹ̀sì.
7. Wọ́n ń sáré bí akọni,wọ́n ń fo ògiri bí ọmọ ogun.Wọ́n tò lọ́wọ̀ọ̀wọ́,ẹnikẹ́ni kò sì yà kúrò ní ọ̀nà tirẹ̀.
8. Wọn kò fi ara gbún ara wọn,olukuluku ń lọ ní ọ̀nà tirẹ̀;wọ́n kọlu àwọn nǹkan ààbò láìní ìdádúró.
9. Wọ́n ń gun odi ìlú,wọ́n ń sáré lórí odi.Wọ́n ń gun orí ilé wọlé,wọ́n gba ojú fèrèsé bẹ́ sinu ọ̀dẹ̀dẹ̀ bí olè.
10. Ilẹ̀ ń mì tìtì níwájú wọn,ọ̀run sì ń wárìrì,oòrùn, òṣùpá ati àwọn ìràwọ̀ ṣókùnkùn.