18. Àwọn ọmọ ń kó igi jọ, àwọn baba wọn ń dá iná, àwọn obinrin ń po ìyẹ̀fun láti fi ṣe àkàrà fún Ayaba Ọ̀run. Wọ́n sì ń ta ọtí sílẹ̀ fún àwọn oriṣa láti mú mi bínú.
19. Ṣé èmi ni wọ́n ń mú bínú? Kì í ṣe pé ara wọn ni wọ́n ń ṣe, tí wọ́n sì ń dójú ti ara wọn?
20. Nítorí náà, èmi OLUWA Ọlọrun óo tú ibinu gbígbóná mi sórí ibí yìí, n óo bínú sí eniyan ati ẹranko, ati igi oko ati èso ilẹ̀. Ibinu mi óo jó wọn run bí iná, kò sì ní ṣe é pa.
21. “Ẹ da ẹbọ sísun yín pọ̀ mọ́ ẹran tí ẹ fi rúbọ, kí ẹ lè rí ẹran jẹ; Èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ni mo sọ bẹ́ẹ̀.
22. Nítorí ní ọjọ́ tí mo kó àwọn baba yín jáde ní ilẹ̀ Ijipti, n kò bá wọn sọ̀rọ̀ ẹbọ sísun tabi ẹbọ rírú, bẹ́ẹ̀ ni n kò pàṣẹ rẹ̀ fún wọn.
23. Àṣẹ tí mo pa fún wọn ni pé kí wọn gbọ́ràn sí mi lẹ́nu. Mo ní n óo máa jẹ́ Ọlọrun wọn, àwọn náà óo sì máa jẹ́ eniyan mi; mo ní kí wọn máa tọ ọ̀nà tí mo bá pa láṣẹ fún wọn, kí ó lè dára fún wọn.
24. Ṣugbọn wọn kò gbọ́ràn, wọn kò sì tẹ́tí sí mi. Wọ́n ń tẹ̀lé ìmọ̀ ara wọn, wọ́n ń ṣe oríkunkun, dípò kí wọ́n máa lọ siwaju, ẹ̀yìn ni wọ́n ń pada sí.
25. Láti ọjọ́ tí àwọn baba ńlá yín ti jáde ní ilẹ̀ Ijipti títí di òní, lojoojumọ ni mò ń rán àwọn wolii iranṣẹ mi sí wọn léraléra.
26. Sibẹ wọn kò gbọ́ tèmi, wọn kò tẹ́tí sí mi. Kàkà bẹ́ẹ̀, oríkunkun ni wọ́n ń ṣe. Iṣẹ́ burúkú wọn ju ti àwọn baba ńlá wọn lọ.
27. “Gbogbo ọ̀rọ̀ wọnyi ni o óo sọ fún wọn, ṣugbọn wọn kò ní gbọ́. O óo pè wọ́n, ṣugbọn wọn kò ní dá ọ lóhùn.
28. O óo sọ fún wọn pé, ‘Ẹ̀yin ni orílẹ̀-èdè tí kò gbọ́ ohùn OLUWA Ọlọrun rẹ̀, tí kò sì gbọ́ ìbáwí. Òtítọ́ kò sí mọ́ ninu ìṣe yín, bẹ́ẹ̀ ni, kò sì sí ninu ọ̀rọ̀ ẹnu yín.’
29. “Ẹ gé irun orí yín dànù,ẹ lọ sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn lórí òkè,nítorí OLUWA ti kọ ìran yín sílẹ̀,ó ti fi ibinu ta ìran yín nù.
30. “Àwọn ọmọ Juda ti ṣe nǹkan burúkú. Wọ́n gbé ère wọn kalẹ̀ ninu ilé tí à ń fi orúkọ mi pè, wọ́n sì ti sọ ọ́ di aláìmọ́.