Jeremaya 25:12-20 BIBELI MIMỌ (BM)

12. Nígbà tí aadọrin ọdún bá pé, n óo jẹ ọba Babiloni ati orílẹ̀-èdè rẹ̀, ati ilẹ̀ àwọn ará Kalidea níyà, nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn. N óo sì sọ ibẹ̀ di àlàpà títí ayé.

13. N óo mú gbogbo ọ̀rọ̀ burúkú tí mo ti sọ nípa ilẹ̀ náà ṣẹ, ati gbogbo ohun tí a kọ sinu ìwé yìí, àní àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tí Jeremaya sọ nípa gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè.

14. Ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè ati àwọn ọba alágbára yóo sọ àwọn ará Babiloni pàápàá di ẹrú, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀san ìṣe wọn ati iṣẹ́ ọwọ́ wọn.”

15. OLUWA Ọlọrun Israẹli sọ fún mi pé, “Gba ife ọtí ibinu yìí lọ́wọ́ mi, kí o fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí n óo rán ọ sí mu.

16. Wọn yóo mu ún, wọn yóo sì máa ta gbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n, wọn yóo máa ṣe bí aṣiwèrè nítorí ogun tí n óo rán sí ààrin wọn.”

17. Mo bá gba ife náà lọ́wọ́ OLUWA, mo sì fún gbogbo orílẹ̀-èdè tí OLUWA rán mi sí mu:

18. Jerusalẹmu ati àwọn ìlú Juda, àwọn ọba ilẹ̀ Juda ati àwọn ìjòyè wọn, kí wọn lè di ahoro ati òkítì àlàpà, nǹkan àrípòṣé ati ohun tí à ń fi í ṣépè, bí ó ti rí ní òní yìí.

19. N óo fún Farao, ọba Ijipti mu, ati àwọn iranṣẹ rẹ̀ ati àwọn ìjòyè rẹ̀, ati gbogbo àwọn eniyan rẹ̀

20. ati àwọn àlejò tí wọ́n wà láàrin wọn. N óo fún gbogbo àwọn ọba Usi mu, ati gbogbo àwọn ọba ilẹ̀ Filistini, (Aṣikeloni, Gasa, Ekironi ati àwọn tí wọ́n kù ní Aṣidodu).

Jeremaya 25