1. Ọ̀rọ̀ tí OLUWA sọ fún Jeremaya nípa ọ̀gbẹlẹ̀ nìyí:
2. “Juda ń ṣọ̀fọ̀,àwọn ẹnubodè ìlú rẹ̀ wà ninu ìnira.Àwọn eniyan inú rẹ̀ ń sọkún ní ilẹ̀ẹ́lẹ̀,igbe àwọn ará Jerusalẹmu sì ta sókè.
3. Àwọn ọlọ́lá ní ìlú rán àwọn iranṣẹ wọn lọ pọn omi,àwọn iranṣẹ dé odò, wọn kò rí omi.Wọ́n gbé ìkòkò omi wọn pada lófìfo,ojú tì wọ́n, ìdààmú dé bá wọn,wọ́n káwọ́ lérí.
4. Nítorí ilẹ̀ tí ó gbẹ,nítorí òjò tí kò rọ̀ ní ilẹ̀ náà,ojú ti àwọn àgbẹ̀, wọ́n káwọ́ lérí.
5. Àgbọ̀nrín inú igbó pàápàá já ọmọ tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ bí sílẹ̀,nítorí kò sí koríko.
6. Àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó dúró lórí òkè,wọ́n ń mí hẹlẹhẹlẹ bí ajáko.Ojú wọn rẹ̀wẹ̀sì, nítorí kò sí koríko.
7. Àwọn eniyan mi ké pè mí wí pé,‘Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀ṣẹ̀ wa ń jẹ́rìí lòdì sí wa,sibẹsibẹ, nítorí orúkọ rẹ, gbà wá.Ọpọlọpọ ìgbà ni a ti pada lẹ́yìn rẹ,a ti ṣẹ̀ ọ́.
8. Ìwọ ìrètí Israẹli,olùgbàlà rẹ̀ ní ìgbà ìṣòro.Kí ló dé tí o óo fi dàbí àlejò ní ilẹ̀ náà?Àní, bí èrò ọ̀nà, tí ó yà láti sùn mọ́jú?
9. Kí ló dé tí o fi dàbí ẹni tí ìdààmú bá;bí alágbára tí kò lè gbani là?Bẹ́ẹ̀ ni o wà láàrin wa, OLUWA,a sì ń fi orúkọ rẹ pè wá,má fi wá sílẹ̀.’ ”
10. OLUWA sọ nípa àwọn eniyan náà pé,“Ó wù wọ́n láti máa ṣáko kiri,wọn kò ṣọ́ ìrìn ẹsẹ̀ wọn;nítorí náà wọn kì í ṣe ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ OLUWA,nisinsinyii OLUWA yóo ranti àìdára wọn,yóo sì jẹ wọ́n níyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn.”