1. Jakọbu ń gbé ilẹ̀ Kenaani, níbi tí àwọn baba rẹ̀ ti ṣe àtìpó.
2. Àkọsílẹ̀ ìran Jakọbu nìyí: Josẹfu jẹ́ ọmọ ọdún mẹtadinlogun ó sì ń bá àwọn arakunrin rẹ̀ tọ́jú agbo ẹran ó wà lọ́dọ̀ àwọn ọmọ Biliha ati àwọn ọmọ Silipa, àwọn aya baba rẹ̀. Josẹfu a sì máa sọ gbogbo àṣìṣe àwọn arakunrin rẹ̀ fún baba wọn.
3. Israẹli fẹ́ràn Josẹfu ju gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀ yòókù lọ, nítorí pé ó ti di arúgbó kí ó tó bí i, nítorí náà ó dá ẹ̀wù aláràbarà kan fún un.
4. Nígbà tí àwọn arakunrin rẹ̀ yòókù rí i pé baba wọn fẹ́ràn Josẹfu ju àwọn lọ, wọ́n kórìíra rẹ̀, wọn kì í sì fi sùúrù bá a sọ̀rọ̀.
5. Ní ọjọ́ kan, Josẹfu lá àlá kan, ó bá rọ́ àlá náà fún àwọn arakunrin rẹ̀, àlá yìí sì jẹ́ kí wọ́n túbọ̀ kórìíra rẹ̀ sí i.
6. Ó sọ fún wọn pé, “Ẹ jọ̀wọ́, ẹ gbọ́ àlá kan tí mo lá.
7. Èmi pẹlu yín, a wà ní oko ní ọjọ́ kan, à ń di ìtí ọkà, mo rí i tí ìtí ọkà tèmi wà lóòró, ó dúró ṣánṣán, àwọn ìtí ọkà tiyín sì yí i ká, wọ́n ń foríbalẹ̀ fún un.”