1. Nígbà tí Rakẹli rí i pé òun kò bímọ fún Jakọbu rárá, ó bẹ̀rẹ̀ sí jowú ẹ̀gbọ́n rẹ̀, ó wí fún Jakọbu pé, “Tí o kò bá fẹ́ kí n kú sí ọ lọ́rùn, fún mi lọ́mọ.”
2. Inú bí Jakọbu pupọ sí ọ̀rọ̀ tí Rakẹli sọ, ó dá a lóhùn pé, “Ṣé èmi ni Ọlọrun tí kò fún ọ lọ́mọ ni?”
3. Rakẹli bá dáhùn, ó ní, “Biliha, iranṣẹbinrin mi nìyí, bá a lòpọ̀, kí ó bímọ sí mi lọ́wọ́, kí èmi náà sì lè ti ipa rẹ̀ di ọlọ́mọ.”
4. Ó bá fún Jakọbu ní Biliha, iranṣẹbinrin rẹ̀ kí ó fi ṣe aya, Jakọbu sì bá a lòpọ̀.
5. Biliha lóyún, ó bí ọmọkunrin kan fún Jakọbu.
6. Rakẹli bá sọ pé, “Ọlọrun dá mi láre, ó gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ̀ mi, ó sì fún mi ní ọmọkunrin kan.” Nítorí náà, ó sọ ọmọ náà ní Dani.
7. Biliha, iranṣẹbinrin Rakẹli tún lóyún, ó bí ọmọkunrin keji fún Jakọbu.
8. Rakẹli bá sọ pé, “Ìjàkadì gidi ni mo bá ẹ̀gbọ́n mi jà, mo sì ṣẹgun,” ó sì sọ ọmọ náà ní Nafutali.
9. Nígbà tí Lea rí i pé òun kò bímọ mọ́, ó fún Jakọbu ní Silipa, iranṣẹbinrin rẹ̀, kí ó fi ṣe aya.
10. Iranṣẹbinrin Lea bí ọmọkunrin kan fún Jakọbu.
11. Lea bá sọ pé, “Oríire.” Ó bá sọ ọmọ náà ní Gadi.
12. Iranṣẹbinrin Lea tún bí ọmọkunrin mìíràn fún Jakọbu.
13. Lea bá ní, “Mo láyọ̀, nítorí pé àwọn obinrin yóo máa pè mí ní Ẹni-Ayọ̀,” nítorí náà ó sọ ọmọ náà ní Aṣeri.