Jẹnẹsisi 14:16-24 BIBELI MIMỌ (BM)

16. Abramu gba gbogbo ìkógun tí wọ́n kó pada, ó gba Lọti, ìbátan rẹ̀ pẹlu ati gbogbo ohun ìní rẹ̀, ati àwọn obinrin ati ọ̀pọ̀ àwọn eniyan mìíràn.

17. Nígbà tí Abramu ń pada bọ̀, lẹ́yìn tí ó ti ṣẹgun Kedorilaomeri ati àwọn ọba tí wọ́n jọ pa ìmọ̀ pọ̀, ọba Sodomu jáde lọ pàdé rẹ̀ ní àfonífojì Ṣafe (tí ó tún ń jẹ́, àfonífojì ọba).

18. Mẹlikisẹdẹki ọba Salẹmu náà mú oúnjẹ ati ọtí waini wá pàdé rẹ̀. Mẹlikisẹdẹki jẹ́ alufaa Ọlọrun Ọ̀gá Ògo.

19. Ó súre fún Abramu, ó ní:“Kí Ọlọrun Ọ̀gá Ògo,tí ó dá ọ̀run ati ayé bukun Abramu.

20. Ìyìn sì ni fún Ọlọrun Ọ̀gá Ògo,ẹni tí ó bá ọ ṣẹgun àwọn ọ̀tá rẹ.”Abramu bá fún Mẹlikisẹdẹki ní ìdámẹ́wàá gbogbo ìkógun tí ó kó bọ̀.

21. Ọba Sodomu sọ fún Abramu pé, “Jọ̀wọ́, máa kó gbogbo ìkógun lọ, ṣugbọn dá àwọn eniyan mi pada fún mi.”

22. Ṣugbọn Abramu dá a lóhùn ó ní: “Mo ti búra fún OLUWA Ọlọrun Ọ̀gá Ògo, ẹni tí ó dá ọ̀run ati ayé,

23. pé, abẹ́rẹ́ lásán, n kò ní fọwọ́ mi kàn ninu ohun tí ó jẹ́ tìrẹ, kí o má baà sọ pé ìwọ ni o sọ mí di ọlọ́rọ̀.

24. N kò ní fọwọ́ mi kan ohunkohun àfi ohun tí àwọn ọmọkunrin tí wọ́n bá mi lọ ti jẹ, ati ìpín tiwọn tí ó kàn wọ́n, ṣugbọn jẹ́ kí Aneri, Eṣikolu ati Mamure kó ìpín tiwọn.”

Jẹnẹsisi 14