Isikiẹli 36:6-11 BIBELI MIMỌ (BM)

6. “Nítorí náà, sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ilẹ̀ Israẹli. Wí fún àwọn òkè ńláńlá ati àwọn òkè kéékèèké, ati àwọn ipa odò ati àwọn àfonífojì, pé èmi OLUWA Ọlọrun ní ìtara ati ìgbónára ni mo fi ń sọ̀rọ̀ nítorí pé ẹ ti jìyà pupọ, ẹ sì ti di ẹni ẹ̀gàn lọ́wọ́ àwọn orílẹ̀-èdè yòókù.

7. Nítorí náà, èmi OLUWA Ọlọrun, ń ṣe ìbúra pé, àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n wà ní àyíká yín yóo di ẹni ẹ̀sín.

8. Ṣugbọn ẹ̀yin òkè Israẹli, igi óo hù lórí yín, wọn óo sì so èso fún Israẹli, àwọn eniyan mi, nítorí pé wọn kò ní pẹ́ pada wálé.

9. Nítorí pé mo wà fun yín, n óo ṣí ojú àánú wò yín, wọn óo dá oko sórí yín, wọn óo sì gbin nǹkan sinu rẹ̀.

10. N óo sọ àwọn ọmọ Israẹli tí ń gbé orí yín di pupọ. Àwọn ìlú yóo rí ẹni máa gbé inú wọn, wọn óo sì tún gbogbo ibi tí ó ti wó kọ́.

11. N óo sọ eniyan ati ẹran ọ̀sìn di pupọ lórí yín, wọn óo máa bímọlémọ, wọn ó sì di ọ̀kẹ́ àìmọye. N óo mú kí eniyan máa gbé orí yín bí ìgbà àtijọ́, nǹkan ó sì dára fun yín ju ti àtẹ̀yìnwá lọ. Ẹ óo wá mọ̀ nígbà náà pé èmi ni OLUWA.

Isikiẹli 36