2. “Ìwọ ọmọ eniyan, sọ àsọtẹ́lẹ̀ kí o fi bá àwọn olùṣọ́-aguntan Israẹli wí, fi àsọtẹ́lẹ̀ bá àwọn olórí Israẹli wí pé, OLUWA Ọlọrun ní, ‘Háà, ẹ̀yin olórí Israẹli tí ẹ̀ ń wá oúnjẹ fún ara yín, ṣé kò yẹ kí olùṣọ́-aguntan máa pèsè oúnjẹ fún àwọn aguntan rẹ̀?
3. Ẹ̀yin ń jẹ ẹran ọlọ́ràá, ẹ̀ ń fi irun aguntan bo ara yín, ẹ̀ ń pa aguntan tí ó sanra jẹ; ṣugbọn ẹ kò fún àwọn aguntan ní oúnjẹ.
4. Ẹ kò tọ́jú àwọn tí wọn kò lágbára, ẹ kò tọ́jú àwọn tí ń ṣàìsàn, ẹ kò tọ́jú ẹsẹ̀ àwọn tí wọn dá lẹ́sẹ̀, ẹ kò mú àwọn tí wọn ń ṣáko lọ pada wálé; ẹ kò sì wá àwọn tí wọ́n sọnù. Pẹlu ipá ati ọwọ́-líle ni ẹ fi ń ṣe àkóso wọn.
5. Nítorí náà, wọ́n túká nítorí pé wọn kò ní olùṣọ́, wọ́n sì di ìjẹ fún àwọn ẹranko burúkú.
6. Àwọn aguntan mi túká, wọ́n ń káàkiri lórí gbogbo òkè ńlá ati gbogbo òkè kéékèèké. Àwọn aguntan mi fọ́n káàkiri sórí gbogbo ilẹ̀ ayé. Kò sí ẹni tí ó bèèrè wọn, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹni tí ó wá wọn.’
7. “Nítorí náà, ẹ̀yin, olùṣọ́-aguntan, ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA wí.
8. OLUWA Ọlọrun fi ara rẹ̀ búra ó ní, ‘Àwọn aguntan mi di ìjẹ, fún gbogbo ẹranko nítorí pé wọn kò ní olùṣọ́; nítorí pé àwọn tí ń ṣọ́ wọn kò wá wọn, kàkà bẹ́ẹ̀ oúnjẹ ni wọ́n ń wá sẹ́nu ara wọn, wọn kò bọ́ àwọn aguntan mi.’
9. Nítorí náà, ẹ gbọ́, ẹ̀yin olùṣọ́-aguntan:
10. ‘Mo lòdì sí ẹ̀yin olùṣọ́-aguntan, n óo sì bèèrè àwọn aguntan mi lọ́wọ́ yín. N óo da yín dúró lẹ́nu iṣẹ́ olùṣọ́-aguntan, ẹ kò sì ní rí ààyè bọ́ ara yín mọ́. N óo gba àwọn aguntan mi lẹ́nu yín, ẹ kò sì ní rí wọn pa jẹ mọ́.’ ”
11. OLUWA Ọlọrun ní, “Ẹ wò ó! Èmi fúnra mi ni n óo wá àwọn aguntan mi, àwárí ni n óo sì wá wọn.
12. Bí olùṣọ́-aguntan tií wá àwọn aguntan rẹ̀ tí ó bá jẹ lọ, bẹ́ẹ̀ ni n óo wá àwọn aguntan mi, n óo sì yọ wọ́n kúrò ninu gbogbo ibi tí wọ́n fọ́nká sí ní ọjọ́ tí ìkùukùu bo ilẹ̀, tí òkùnkùn sì ṣú.
13. N óo mú wọn jáde kúrò láàrin àwọn orílẹ̀-èdè yòókù, n óo kó wọn jọ láti gbogbo ilẹ̀ ayé, n óo sì kó wọn wá sí ilẹ̀ tiwọn. N óo máa bọ́ wọn lórí àwọn òkè Israẹli, lẹ́bàá orísun omi ati gbogbo ibi tí àwọn eniyan ń gbé ní Israẹli.
14. N óo fún wọn ní koríko tí ó dára jẹ, orí òkè Israẹli sì ni wọn óo ti máa jẹ koríko. Níbẹ̀, ninu pápá oko tí ó dára ni wọn óo dùbúlẹ̀ sí; ninu pápá oko tútù, wọn yóo sì máa jẹ lórí àwọn òkè Israẹli.
15. Èmi fúnra mi ni n óo jẹ́ olùṣọ́ àwọn aguntan mi, n óo sì mú wọn dùbúlẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni èmi OLUWA Ọlọrun sọ.