Isikiẹli 17:15-24 BIBELI MIMỌ (BM)

15. Ṣugbọn ọba Juda ṣọ̀tẹ̀ sí ti Babiloni, ó rán ikọ̀ lọ sí Ijipti pé kí wọ́n fún òun ní ẹṣin ati ọpọlọpọ ọmọ ogun. Ǹjẹ́ yóo ní àṣeyọrí? Ṣé ẹni tí ń ṣé irú èyí lè bọ́? Ṣé ó lè yẹ majẹmu náà kí ó sì bọ́ ninu rẹ̀?

16. “Èmi OLUWA fi ara mi búra pé, ní ilẹ̀ Babiloni, ní ilẹ̀ ọba tí ó fi í sórí oyè ọba tí kò náání, tí ó sì da majẹmu rẹ̀, níbẹ̀ ni yóo kú sí.

17. Farao, pẹlu ogunlọ́gọ̀ àwọn ọmọ ogun rẹ̀, ati ọpọlọpọ eniyan rẹ̀, kò ní lè ràn án lọ́wọ́ nígbà ogun; nígbà tí ogun bá dótì í, tí wọ́n sì mọ òkítì sí ara odi rẹ̀ láti pa ọpọlọpọ eniyan.

18. Kò ní sá àsálà, nítorí pé kò náání ìbúra ó sì da majẹmu, ati pé ó ti tọwọ́ bọ ìwé, sibẹsibẹ, ó tún ṣe gbogbo nǹkan tí ó ṣe.”

19. Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun ní, “Mo fi ara mi búra, n óo gbẹ̀san ìbúra mi tí kò náání lára rẹ̀, ati majẹmu mi tí ó dà.

20. N óo da àwọ̀n mi bò ó mọ́lẹ̀, pańpẹ́ mi yóo mú un, n óo sì mú un lọ sí Babiloni. Níbẹ̀ ni n óo ti ṣe ìdájọ́ rẹ̀ nítorí ìwà ọ̀tẹ̀ tí ó hù sí mi.

21. Idà ni wọn óo fi pa àwọn tí wọ́n bá sá lára àwọn ọmọ ogun rẹ̀, a óo sì fọ́n àwọn tí wọ́n bá kù ká sí gbogbo ayé, ẹ óo wá mọ̀ pé èmi OLUWA ni mo sọ̀rọ̀.”

22. OLUWA Ọlọrun ní:“Èmi fúnra mi ni n óo mú ọ̀kan ninu ẹ̀ka kan ní ṣóńṣó igi Kedari gíga,n óo ṣẹ́ ẹ̀ka kan láti orí rẹ̀,n óo gbìn ín sí orí òkè gíga fíofío.

23. Lórí òkè gíga Israẹli ni n óo gbìn ín sí,kí ó lè yọ ẹ̀ka, kí ó so,kí ó sì di igi Kedari ńlá.Oríṣìíríṣìí ẹranko ìgbẹ́ ni yóo máa gbé abẹ́ rẹ̀.Oríṣìíríṣìí ẹyẹ yóo pa ìtẹ́ sí abẹ́ òjìji ẹ̀ka rẹ̀.

24. Gbogbo igi inú igbó yóo mọ̀ péèmi, OLUWA, ni èmi í sọ igi ńlá di kékeré,mà sì máa sọ igi kékeré di ńlá.Mà máa sọ igi tútù di gbígbẹ,má sì máa mú kí igi gbígbẹ pada rúwé.Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀,bẹ́ẹ̀ ni n óo sì ṣe.”

Isikiẹli 17