11. OLUWA bínú gidigidi,ó tú ibinu gbígbóná rẹ̀ jáde.OLUWA dá iná kan ní Sioni tí ó jó ìpìlẹ̀ rẹ̀ run.
12. Àwọn ọba ayé kò gbàgbọ́,bẹ́ẹ̀ ni gbogbo aráyé kò gbà pé ó lè ṣẹlẹ̀,pé ọ̀tá lè wọ ẹnubodè Jerusalẹmu.
13. Ẹ̀ṣẹ̀ àwọn wolii rẹ̀ ló fa èyí,ati àìdára àwọn alufaa rẹ̀,tí wọ́n pa olódodo láàrin ìlú.
14. Wọ́n ń káàkiri bí afọ́jú láàrin ìgboro,ẹ̀jẹ̀ àwọn tí wọ́n pa sọ wọ́n di aláìmọ́tóbẹ́ẹ̀ tí ẹnikẹ́ni kò lè fọwọ́ kan aṣọ wọn.
15. Àwọn eniyan ń kígbe lé wọn lórí pé;“Ẹ máa lọ! Ẹ̀yin aláìmọ́!Ẹ máa kóra yín lọ! Ẹ má fi ọwọ́ kan nǹkankan!”Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe di ìsáǹsá ati alárìnkiri,nítorí àwọn eniyan ń wí láàrin gbogbo orílẹ̀-èdè pé,“Àwọn wọnyi kò gbọdọ̀ bá wa gbé pọ̀ mọ́.”
16. OLUWA fúnrarẹ̀ ti tú wọn ká,kò sì ní náání wọn mọ́.Kò ní bọlá fún àwọn alufaa wọn,kò sì ní fi ojurere wo àwọn àgbààgbà.
17. A wọ̀nà títí ojú wa di bàìbàì,asán ni ìrànlọ́wọ́ tí à ń retí jásí.A wọ̀nà títí fún ìrànlọ́wọ́lọ́dọ̀ orílẹ̀-èdè tí kò lè gbani là.
18. Àwọn eniyan ń ṣọ́ ìrìn ẹsẹ̀ wa,tóbẹ́ẹ̀ tí a kò lè rìn gaara ní ìgboro.Ìparun wa súnmọ́lé,ọjọ́ ayé wa ti níye,nítorí ìparun wa ti dé.
19. Àwọn tí wọn ń lépa wa yáraju idì tí ń fò lójú ọ̀run lọ.Wọ́n ń lé wa lórí òkè,wọ́n sì ba dè wá ninu aṣálẹ̀.