Ẹkún Jeremaya 2:1-4 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ẹ wò bí OLUWA ti fi ibinufi ìkùukùu bo Sioni mọ́lẹ̀.Ó ti wọ́ ògo Israẹli luláti òkè ọ̀run sórí ilẹ̀ ayé;kò tilẹ̀ ranti àpótí ìtìsẹ̀ rẹ̀ ní ọjọ́ ibinu rẹ̀.

2. OLUWA ti pa gbogbo ibùgbé Jakọbu run láìsí àánú.Ó ti fi ibinu wó ibi ààbò Juda lulẹ̀.Ó ti rẹ ìjọba ati àwọn aláṣẹ rẹ̀ sílẹ̀,ó fi àbùkù kàn wọ́n.

3. Ó ti fi ibinu gbígbóná rẹ̀,pa àwọn alágbára Israẹli;ó kọ̀, kò ràn wọ́n lọ́wọ́,nígbà tí àwọn ọ̀tá dojú kọ wọ́n.Ó jó àwọn ọmọ Jakọbu bí iná,ó sì pa gbogbo ohun tí wọn ní run.

4. Ó kẹ́ ọfà rẹ̀ bí ọ̀tá,ó múra bí aninilára.Gbogbo ògo wa ló parun lójú wa,ó sì tú ibinu rẹ̀ jáde bí iná, ninu àgọ́ Sioni.

Ẹkún Jeremaya 2