4. Ṣugbọn gbogbo ẹ̀yin tí ẹ di OLUWA Ọlọrun yín mú ṣinṣin ni ẹ wà láàyè títí di òní.
5. “Mo ti kọ yín ní ìlànà ati òfin gẹ́gẹ́ bí OLUWA Ọlọrun ti pa á láṣẹ fún mi, kí ẹ lè máa tẹ̀lé wọn nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ tí ẹ̀ ń lọ gbà.
6. Ẹ máa pa wọ́n mọ́, kí ẹ sì máa tẹ̀lé wọn, wọn yóo sì sọ yín di ọlọ́gbọ́n ati olóye lójú àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn. Orílẹ̀-èdè tí ó bá gbọ́ nípa àwọn ìlànà ati òfin wọnyi yóo wí pé, dájúdájú ọlọ́gbọ́n ati amòye eniyan ni yín.
7. “Ǹjẹ́, orílẹ̀-èdè ńlá wo ni ó tún wà, tí ó ní oriṣa tí ó súnmọ́ ọn gẹ́gẹ́ bí OLUWA Ọlọrun tií súnmọ́ wa nígbàkúùgbà tí a bá pè é?
8. Tabi orílẹ̀-èdè ńlá wo ni ó tún wà, tí ó ní ìlànà ati òfin òdodo gẹ́gẹ́ bí àwọn tí mo gbé ka iwájú yín lónìí?
9. Ẹ ṣọ́ra gidigidi, kí ẹ sì ṣe pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́, kí ẹ má baà gbàgbé àwọn ohun tí ẹ ti fi ojú ara yín rí, kí iyè yín má baà fò wọ́n ní gbogbo ọjọ́ ayé yín. Ẹ máa pa á nítàn fún àwọn ọmọ yín ati àwọn ọmọ ọmọ yín,
10. gẹ́gẹ́ bí ẹ ti dúró níwájú OLUWA Ọlọrun yín lẹ́bàá òkè Sinai, tí ó fi sọ fún mi pé, ‘Pe àwọn eniyan náà jọ sọ́dọ̀ mi, kí wọ́n lè gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, kí wọ́n lè kọ́ láti máa bẹ̀rù mi ní gbogbo ọjọ́ ayé wọn; kí wọ́n sì kọ́ àwọn ọmọ wọn pẹlu.’
11. “Lẹ́yìn náà, ẹ súnmọ́ òkè náà, nígbà tí ó ń jóná, tóbẹ́ẹ̀ tí ahọ́n iná náà fẹ́rẹ̀ kan ojú ọ̀run, tí òkùnkùn ati ìkùukùu bo òkè náà.
12. Ọlọrun ba yín sọ̀rọ̀ láti inú iná náà wá, ẹ gbọ́ ohùn rẹ̀, ṣugbọn ẹ kò rí i. Ohùn rẹ̀ nìkan ni ẹ̀ ń gbọ́.
13. Ó sọ majẹmu rẹ̀ fun yín, tíí ṣe àwọn òfin mẹ́wàá tí ó pa láṣẹ fun yín láti tẹ̀lé, ó sì kọ wọ́n sí orí tabili òkúta meji.
14. OLUWA pàṣẹ fún mi nígbà náà, láti kọ yín ní ìlànà ati òfin rẹ̀, kí ẹ lè máa tẹ̀lé wọn ní ilẹ̀ tí ẹ̀ ń lọ gbà.
15. “Nítorí náà, ẹ ṣọ́ra gidigidi, níwọ̀n ìgbà tí ẹ kò rí ìrísí OLUWA ní ọjọ́ tí ó ba yín sọ̀rọ̀ láàrin iná ní Horebu,