Diutaronomi 27:4-16 BIBELI MIMỌ (BM)

4. Nígbà tí ẹ bá rékọjá sí òdìkejì odò Jọdani, ẹ to àwọn òkúta tí mo paláṣẹ fun yín lónìí jọ lórí òkè Ebali, kí ẹ sì fi ohun tí wọ́n fi ń rẹ́ ilé rẹ́ ẹ.

5. Ẹ fi òkúta kọ́ pẹpẹ kan fún OLUWA níbẹ̀; ẹ kò gbọdọ̀ fi irin gbẹ́ òkúta náà rárá.

6. Òkúta tí wọn kò gbẹ́ ni kí ẹ fi kọ́ pẹpẹ kan fún OLUWA Ọlọrun yín kí ẹ sì rú ẹbọ sísun sí i lórí rẹ̀.

7. Ẹ rú ẹbọ alaafia, kí ẹ jẹ ẹ́ níbẹ̀, kí ẹ sì máa yọ̀ níwájú OLUWA Ọlọrun yín.

8. Ẹ kọ gbogbo àwọn òfin wọnyi sára òkúta náà, ẹ kọ wọ́n kí wọ́n hàn ketekete.”

9. Mose ati àwọn alufaa, ọmọ Lefi, bá wí fún gbogbo ọmọ Israẹli pé, “Ẹ dákẹ́ jẹ́ẹ́, kí ẹ sì gbọ́, ẹ̀yin ọmọ Israẹli, òní ni ẹ di eniyan OLUWA Ọlọrun yín.

10. Nítorí náà ẹ gbọdọ̀ máa gbọ́ràn sí OLUWA Ọlọrun yín lẹ́nu, kí ẹ sì máa pa òfin ati ìdájọ́ rẹ̀ mọ́, bí èmi Mose ti pàṣẹ fun yín lónìí.”

11. Mose bá pàṣẹ fún àwọn eniyan náà ní ọjọ́ kan náà, ó ní,

12. “Nígbà tí ẹ bá kọjá odò Jọdani sí òdìkejì, àwọn ẹ̀yà Simeoni, ẹ̀yà Lefi, ti Juda, ti Isakari, ti Josẹfu ati ti Bẹnjamini yóo dúró lórí òkè Gerisimu láti súre.

13. Àwọn ẹ̀yà Reubẹni, ẹ̀yà Gadi, ti Aṣeri, ti Sebuluni, ti Dani ati ti Nafutali yóo sì dúró lórí òkè Ebali láti búra.

14. Àwọn ọmọ Lefi yóo wí ketekete fún gbogbo àwọn ọmọ Israẹli pé:

15. “ ‘Ẹni ìfibú ni ẹnikẹ́ni tí ó bá yá ère gbígbẹ́ tabi ère tí wọ́n fi irin rọ. Ohun ìríra ni lójú OLUWA, pé kí àwọn gbẹ́nàgbẹ́nà fi ọwọ́ gbẹ́ nǹkan, kí ẹnìkan wá gbé e kalẹ̀ níkọ̀kọ̀, kí ó máa bọ ọ́.’“Gbogbo àwọn eniyan yóo sì dáhùn pé, ‘Amin.’

16. “ ‘Ẹni ìfibú ni ẹnikẹ́ni tí ó bá tàbùkù baba tabi ìyá rẹ̀.’“Gbogbo eniyan yóo sì dáhùn pé, ‘Amin.’

Diutaronomi 27