1. “Ọkunrin tí wọ́n bá tẹ̀ lọ́dàá, tabi tí wọ́n bá gé nǹkan ọkunrin rẹ̀, kò gbọdọ̀ bá ìjọ eniyan OLUWA péjọ.
2. “Ọmọ àlè kankan kò gbọdọ̀ bá ìjọ eniyan OLUWA péjọ, arọmọdọmọ rẹ̀ títí dé ìran kẹwaa kò gbọdọ̀ bá ìjọ eniyan OLUWA péjọ.
3. “Ará Amoni ati Moabu kankan kò gbọdọ̀ bá ìjọ eniyan OLUWA péjọ, arọmọdọmọ wọn títí dé ìran kẹwaa kò gbọdọ̀ bá ìjọ eniyan OLUWA péjọ;
4. nítorí pé, nígbà tí ẹ̀ ń bọ̀ láti ilẹ̀ Ijipti, wọn kò gbé oúnjẹ ati omi pàdé yín. Kàkà bẹ́ẹ̀, Balaamu ọmọ Beori ará Petori, ní Mesopotamia, ni wọ́n bẹ̀ pé kí ó wá gbé yín ṣépè.
5. Ṣugbọn OLUWA Ọlọrun yín kò fetí sí ti Balaamu, ó yí èpè náà sí ìre fun yín nítorí pé ó fẹ́ràn yín.
6. Ẹ kò gbọdọ̀ ro ire kàn wọ́n tabi kí ẹ wá ìtẹ̀síwájú wọn títí lae.
7. “Ẹ kò gbọdọ̀ kórìíra àwọn ọmọ Edomu, nítorí pé arakunrin yín ni wọ́n. Ẹ kò gbọdọ̀ kórìíra àwọn ará Ijipti nítorí pé ẹ ti ṣe àtìpó ní ilẹ̀ wọn rí.
8. Bẹ̀rẹ̀ láti ìran kẹta wọn, wọ́n lè bá ìjọ eniyan OLUWA péjọ.
9. “Nígbà tí ẹ bá jáde lọ láti bá àwọn ọ̀tá yín jagun, tí ẹ bá sì wà ninu àgọ́, ẹ níláti yẹra fún ohunkohun tíí ṣe ibi.
10. Bí ọkunrin kan bá wà ninu yín tí ó di aláìmọ́ nítorí ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí i láàrin òru, kí irú ẹni bẹ́ẹ̀ jáde kúrò ninu àgọ́. Kò gbọdọ̀ wọ inú àgọ́ wá mọ́.
11. Ṣugbọn nígbà tí ó bá di ìrọ̀lẹ́, kí ó wẹ̀. Nígbà tí oòrùn bá sì wọ̀, ó lè wọ inú àgọ́ wá.
12. “Ẹ gbọdọ̀ ní ibìkan lẹ́yìn àgọ́ tí ẹ óo máa yàgbẹ́ sí.
13. Kí olukuluku yín ní ọ̀pá kan, tí yóo máa dì mọ́ ara ohun ìjà rẹ̀, tí ó lè fi gbẹ́lẹ̀ nígbà tí ó bá fẹ́ yàgbẹ́; nígbà tí ó bá sì yàgbẹ́ tán, ọ̀pá yìí ni yóo fi wa erùpẹ̀ bò ó mọ́lẹ̀.
14. Nítorí pé, OLUWA Ọlọrun yín wà pẹlu yín ninu àgọ́ láti gbà yín là, ati láti jẹ́ kí ọwọ́ yín tẹ àwọn ọ̀tá yín. Nítorí náà, àgọ́ yín níláti jẹ́ mímọ́, kí OLUWA má baà rí ohunkohun tí ó jẹ́ àìmọ́ láàrin yín, kí ó sì yipada kúrò lọ́dọ̀ yín.
15. “Bí ẹrú kan bá sá kúrò lọ́dọ̀ ọ̀gá rẹ̀, tí ó bá tọ̀ yín wá, ẹ kò gbọdọ̀ lé e pada sọ́dọ̀ ọ̀gá rẹ̀.