8. Ẹ gbọdọ̀ lawọ́ sí i, kí ẹ sì yá a ní ohun tí ó tó láti tán gbogbo àìní rẹ̀, ohunkohun tí ó wù kí ó lè jẹ́.
9. Ẹ ṣọ́ra, kí èròkerò má baà gba ọkàn yín, kí ẹ wí pé, ọdún keje tíí ṣe ọdún ìdásílẹ̀ ti súnmọ́ tòsí, kí ojú yín sì le sí arakunrin yín tí ó jẹ́ talaka, kí ẹ má sì fún un ní ohunkohun. Kí ó má baà ké pe OLUWA nítorí yín, kí ó sì di ẹ̀ṣẹ̀ si yín lọ́rùn.
10. Ẹ fún un ní ohun tí ẹ bá fẹ́ fún un tọkàntọkàn, kì í ṣe pẹlu ìkùnsínú, nítorí pé, nítorí ìdí èyí ni OLUWA Ọlọrun yín yóo ṣe bukun iṣẹ́ ọwọ́ yín ati gbogbo ohun tí ẹ bá dáwọ́ lé.
11. Nítorí pé, talaka kò ní tán lórí ilẹ̀ yín, nítorí náà ni mo ṣe ń pàṣẹ fun yín pé kí ẹ lawọ́ sí arakunrin yín, ati sí talaka ati sí aláìní ní ilẹ̀ náà.
12. “Bí wọ́n bá ta arakunrin yín lẹ́rú fun yín, kì báà jẹ́ ọkunrin tabi obinrin, tí ó bá ti jẹ́ Heberu, ọdún mẹfa ni yóo fi sìn yín. Tí ó bá di ọdún keje, ẹ gbọdọ̀ dá a sílẹ̀, kí ó sì máa lọ.
13. Nígbà tí ẹ bá dá a sílẹ̀ pé kí ó máa lọ, ẹ kò gbọdọ̀ jẹ́ kí ó lọ ní ọwọ́ òfo.
14. Ẹ gbọdọ̀ fún un ní ẹran ọ̀sìn lọpọlọpọ ati ọkà láti inú ibi ìpakà yín, ati ọtí waini. Bí OLUWA Ọlọrun yín bá ti bukun yín tó, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ ṣe fún un tó.
15. Ẹ gbọdọ̀ ranti pé ẹ̀yin náà ti jẹ́ ẹrú rí ní ilẹ̀ Ijipti, OLUWA Ọlọrun yín ni ó rà yín pada; nítorí náà ni mo fi ń pàṣẹ fun yín lónìí.
16. “Ṣugbọn tí ó bá wí fun yín pé, òun kò ní jáde ninu ilé yín, nítorí pé ó fẹ́ràn ẹ̀yin ati gbogbo ìdílé yín, nítorí pé ó dára fún un nígbà tí ó wà lọ́dọ̀ yín,
17. ẹ mú ìlutí kan, kí ẹ fi lu etí rẹ̀ mọ́ ara ìlẹ̀kùn. Yóo sì jẹ́ ẹrukunrin yín títí lae. Bí ó bá sì jẹ́ obinrin ni, bákan náà ni kí ẹ ṣe fún un.
18. Má jẹ́ kí ó ni ọ́ lára láti dá a sílẹ̀ kí ó sì máa lọ lọ́fẹ̀ẹ́, nítorí pé, ìdajì owó ọ̀yà alágbàṣe ni ó ti fi ń sìn ọ́, fún odidi ọdún mẹfa. Bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ ṣe, kí OLUWA Ọlọrun yín lè bukun ohun gbogbo tí ẹ bá ń ṣe.
19. “Gbogbo àkọ́bí tí ẹran ọ̀sìn bá bí ninu agbo ẹran yín, tí ó bá jẹ́ akọ ni ẹ gbọdọ̀ yà á sọ́tọ̀ fún OLUWA Ọlọrun. Ẹ kò gbọdọ̀ fi akọ tí ó jẹ́ àkọ́bí ninu agbo mààlúù yín ṣiṣẹ́, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò sì gbọdọ̀ rẹ́ irun àgbò tí ó jẹ́ àkọ́bí aguntan yín.
20. Níbikíbi tí OLUWA Ọlọrun yín bá yàn, ni ẹ ti gbọdọ̀ máa jẹ wọ́n níwájú rẹ̀, ní ọdọọdún; ẹ̀yin ati gbogbo ilé yín.
21. Ṣugbọn bí ó bá ní àbààwọ́n kan, bóyá ó jẹ́ arọ ni, tabi afọ́jú, tabi ó ní àbààwọ́n kankan, ẹ kò gbọdọ̀ fi rúbọ sí OLUWA Ọlọrun yín,
22. jíjẹ ni kí ẹ jẹ ẹ́ ní ààrin ìlú yín, ati àwọn tí wọ́n mọ́, ati àwọn tí wọ́n jẹ́ aláìmọ́ ni wọ́n lè jẹ ninu rẹ̀, bí ìgbà tí eniyan jẹ ẹran èsúó tabi àgbọ̀nrín ni.