13. Ẹni mímọ́ kan sọ̀rọ̀; mo tún gbọ́ tí ẹni mímọ́ mìíràn dá ẹni tí ó kọ́ sọ̀rọ̀ lóhùn pé, “Ìran nípa ẹbọ sísun ojoojumọ yóo ti pẹ́ tó; ati ti ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ń sọ nǹkan di ahoro; ati ìran nípa pípa ibi mímọ́ tì, ati ti àwọn ọmọ ogun tí wọ́n di ìtẹ̀mọ́lẹ̀?”
14. Mo gbọ́ tí ẹni mímọ́ náà dáhùn pé, “Nǹkan wọnyi yóo máa rí báyìí lọ títí fún ẹgbaa ó lé ọọdunrun (2,300) ọdún, lẹ́yìn náà a óo ya ibi mímọ́ sí mímọ́.”
15. Nígbà tí èmi Daniẹli rí ìran náà, bí mo ti bẹ̀rẹ̀ sí wá ọ̀nà láti mọ ìtumọ̀ rẹ̀, ni ẹnìkan bá yọ níwájú mi tí ó dàbí eniyan.
16. Mo gbóhùn ẹnìkan láàrin bèbè kinni keji odò Ulai tí ó wí pé, “Geburẹli, sọ ìtumọ̀ ìran tí ọkunrin yìí rí fún un.”
17. Ó wá sí ẹ̀bá ibi tí mo dúró sí. Bí mo ti rí i, ẹ̀rù bà mí, mo dojúbolẹ̀.Ó bá sọ fún mi pé, “Ìwọ ọmọ eniyan, mo fẹ́ kí o mọ̀ pé ìran ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ọ̀la ni ohun tí o rí.”
18. Bí ó ti ń bá mi sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, mo sùn lọ fọnfọn, mo dojúbolẹ̀. Ó bá fọwọ́ kàn mí, ó sì gbé mi dìde,
19. ó ní, “Ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ kẹ́yìn ibinu Ọlọrun sí àwọn eniyan lẹ́yìn ọ̀la ni ìran tí o rí.
20. “Àwọn ọba Pasia ati Media ni àgbò tí o rí, tí ó ní ìwo meji lórí.
21. Ìjọba Giriki ni òbúkọ onírun jákujàku tí o rí. Ọba àkọ́kọ́ tí yóo jẹ níbẹ̀ ni ìwo ńlá tí ó wà láàrin ojú rẹ̀.
22. Ìtumọ̀ ìwo tí ó ṣẹ́, tí mẹrin mìíràn sì hù dípò rẹ̀, ni pé lẹ́yìn ikú rẹ̀ ni ìjọba rẹ̀ yóo pín sí mẹrin, ṣugbọn kò ní jẹ́ láti ọwọ́ rẹ̀.
23. “Nígbà tí ìjọba wọn bá ń lọ sópin, tí ẹ̀ṣẹ̀ wọn bá kún ojú ìwọ̀n, ọba kan tí ojú rẹ̀ le, tí ó ní àrékérekè, tí ó sì lágbára yóo gorí oyè.
24. Agbára rẹ̀ yóo pọ̀, ṣugbọn kò ní jẹ́ nípa ipá rẹ̀, yóo máa ṣe àṣeyọrí ninu gbogbo ohun tí ó bá ń ṣe, yóo sì mú kí á run àwọn eniyan Ọlọrun ati àwọn alágbára.
25. Nípa ọgbọ́n àrékérekè rẹ̀, yóo máa tan àwọn eniyan jẹ, ìgbéraga yóo kún ọkàn rẹ̀, yóo máa pa ọpọlọpọ eniyan lójijì, yóo sì lòdì sí ọba tí ó ju gbogbo àwọn ọba lọ. Ṣugbọn yóo parun láìní ọwọ́ ẹnikẹ́ni ninu.
26. Ìran ti ẹbọ àṣáálẹ́ ati ti òwúrọ̀ tí a ti là yé ọ yóo ṣẹ dájúdájú; ṣugbọn, pa àṣírí ìran yìí mọ́ nítorí ọjọ́ tí yóo ṣẹ ṣì jìnnà.”