Daniẹli 12:5-12 BIBELI MIMỌ (BM)

5. Nígbà náà ni mo rí i tí àwọn meji dúró létí bèbè odò kan, ọ̀kan lápá ìhín, ọ̀kan lápá ọ̀hún.

6. Ọ̀kan ninu wọn bi ẹni tí ó wọ aṣọ funfun, tí ó wà lókè odò pé, “Nígbà wo ni àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ń bani lẹ́rù wọnyi yóo dópin?”

7. Ọkunrin tí ó wọ aṣọ funfun, tí ó wà lókè odò na ọwọ́ rẹ̀ mejeeji sókè ọ̀run, mo sì gbọ́ tí ó fi orúkọ ẹni tí ó wà láàyè títí lae búra pé, “Ọdún mẹta ààbọ̀ ni yóo jẹ́. Nígbà tí wọn bá gba agbára lọ́wọ́ àwọn eniyan Ọlọrun patapata, ni gbogbo nǹkan wọnyi yóo ṣẹlẹ̀.”

8. Mo gbọ́ tí ó ń sọ̀rọ̀, ṣugbọn ohun tí ń sọ kò yé mi. Mo bá bèèrè pé, “Olúwa mi, níbo ni nǹkan wọnyi yóo yọrí sí?”

9. Ó dáhùn pé, “Ìwọ Daniẹli, máa bá tìrẹ lọ, nítorí a ti pa ọ̀rọ̀ yìí mọ́, a sì ti fi èdìdì dì í, títí di àkókò ìkẹyìn.

10. Ọ̀pọ̀ eniyan ni yóo wẹ ara wọn mọ́, tí wọn yóo sọ ara wọn di funfun, wọn yóo sì mọ́; ṣugbọn àwọn ẹni ibi yóo máa ṣe ibi; kò ní sí ẹni ibi tí òye yóo yé; ṣugbọn yóo yé àwọn ọlọ́gbọ́n.

11. “Láti ìgbà tí wọn yóo mú ẹbọ ojoojumọ kúrò, tí wọn yóo gbé ohun ìríra sí ibi mímọ́, yóo jẹ́ eedegbeje ọjọ́ ó dín ọjọ́ mẹ́wàá (1,290).

12. Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ó bá forítì í ní gbogbo eedegbeje ọjọ́ ó lé ọjọ́ marundinlogoji (1,335) náà.

Daniẹli 12