39. Ó ní òun óo jẹ arọmọdọmọ Dafidi níyà nítorí ẹ̀ṣẹ̀ Solomoni, ṣugbọn kò ní jẹ́ títí ayé.”
40. Nítorí ọ̀rọ̀ yìí, Solomoni ń wá ọ̀nà láti pa Jeroboamu, ṣugbọn Jeroboamu sá lọ sọ́dọ̀ Ṣiṣaki, ọba Ijipti, níbẹ̀ ni ó sì wà títí tí Solomoni fi kú.
41. Àwọn nǹkan yòókù tí Solomoni ṣe: gbogbo iṣẹ́ rẹ̀, ati ọgbọ́n rẹ̀, ni a kọ sinu Ìwé Ìṣe Solomoni.
42. Ogoji ọdún ni ó fi jọba lórí gbogbo Israẹli ní Jerusalẹmu.
43. Nígbà tí ó kú, wọ́n sin ín sí ìlú Dafidi, baba rẹ̀, Rehoboamu, ọmọ rẹ̀ sì jọba lẹ́yìn rẹ̀.