Àwọn Adájọ́ 6:13-24 BIBELI MIMỌ (BM)

13. Gideoni dá a lóhùn, ó ní “Jọ̀wọ́, oluwa mi, bí OLUWA bá wà pẹlu wa, kí ló dé tí gbogbo nǹkan wọnyi fi ń ṣẹlẹ̀ sí wa? Níbo sì ni gbogbo àwọn iṣẹ́ ìyanu OLUWA wà, tí àwọn baba wa máa ń sọ fún wa nípa rẹ̀, pé, ‘Ṣebí OLUWA ni ó kó wa jáde láti ilẹ̀ Ijipti?’ Ṣugbọn nisinsinyii OLUWA ti kọ̀ wá sílẹ̀, ó sì ti fi wá lé àwọn ará Midiani lọ́wọ́.”

14. Ṣugbọn OLUWA yipada sí i, ó sì dá a lóhùn pé, “Lọ pẹlu agbára rẹ yìí, kí o sì gba Israẹli kúrò lọ́wọ́ àwọn ará Midiani, ṣebí èmi ni mo rán ọ.”

15. Gideoni dáhùn, ó ní, “Sọ fún mi OLUWA, báwo ni mo ṣe lè gba Israẹli sílẹ̀? Ìran mi ni ó rẹ̀yìn jùlọ ninu ẹ̀yà Manase, èmi ni mo sì kéré jù ní ìdílé wa.”

16. OLUWA dá a lóhùn, ó ní, “N óo wà pẹlu rẹ, o óo sì run àwọn ará Midiani bí ẹni pé, ẹyọ ẹnìkan péré ni wọ́n.”

17. Gideoni tún dáhùn, ó ní, “Bí inú rẹ bá yọ́ sí mi, fi àmì kan hàn mí pé ìwọ OLUWA ni ò ń bá mi sọ̀rọ̀.

18. Jọ̀wọ́, má kúrò níhìn-ín títí tí n óo fi mú ẹ̀bùn mi dé, tí n óo sì gbé e kalẹ̀ níwájú rẹ.”Angẹli náà dá Gideoni lóhùn, ó ní, “N óo dúró títí tí o óo fi pada dé.”

19. Gideoni bá wọlé lọ, ó tọ́jú ọmọ ewúrẹ́ kan, ó sì fi ìyẹ̀fun ìwọ̀n efa kan ṣe burẹdi tí kò ní ìwúkàrà ninu. Ó kó ẹran tí ó sè sinu agbọ̀n kan, ó da omi ọbẹ̀ rẹ̀ sinu ìkòkò kan, ó gbé e tọ Angẹli OLUWA náà lọ ní abẹ́ igi Oaku, ó sì gbé wọn kalẹ̀ níwájú rẹ̀.

20. Angẹli Ọlọrun náà wí fún un pé, “Da ẹran náà ati burẹdi tí kò ní ìwúkàrà ninu náà sí orí àpáta yìí, kí o sì da omi ọbẹ̀ náà lé gbogbo rẹ̀ lórí.” Gideoni sì ṣe bẹ́ẹ̀.

21. Angẹli OLUWA náà bá na ọ̀pá tí ó wà ní ọwọ́ rẹ̀, ó sì fi ṣóńṣó orí rẹ̀ kan ẹran ati burẹdi tí kò ní ìwúkàrà ninu náà; iná bá ṣẹ́ lára àpáta, ó sì jó ẹran ati burẹdi tí kò ní ìwúkàrà ninu náà. Angẹli OLUWA náà bá rá mọ́ ọn lójú.

22. Nígbà náà ni Gideoni tó mọ̀ pé angẹli OLUWA ni, ó bá dáhùn pé, “Yéè! OLUWA Ọlọrun, mo gbé! Nítorí pé mo ti rí angẹli OLUWA lojukooju.”

23. Ṣugbọn OLUWA dá a lóhùn pé, “Alaafia ni, má bẹ̀rù, o kò ní kú.”

24. Gideoni bá tẹ́ pẹpẹ kan níbẹ̀ fún OLUWA, ó pe orúkọ rẹ̀ ní “OLUWA ni Alaafia.” Pẹpẹ náà wà ní Ofira ti ìdílé Abieseri títí di òní olónìí.

Àwọn Adájọ́ 6