5. Wọ́n bá bẹ̀ ẹ́ pé, “Jọ̀wọ́, bá wa wádìí lọ́dọ̀ Ọlọrun, kí á lè mọ̀ bóyá ìrìn àjò tí à ń lọ yìí yóo yọrí sí rere.”
6. Alufaa náà dá wọn lóhùn pé, “Ẹ máa lọ ní alaafia, Ọlọrun fọwọ́ sí ìrìn àjò tí ẹ̀ ń lọ.”
7. Àwọn ọkunrin marun-un náà bá kúrò níbẹ̀, wọ́n wá sí Laiṣi, wọ́n sì rí àwọn eniyan tí wọ́n wà níbẹ̀ bí wọ́n ti ń gbé ní àìléwu gẹ́gẹ́ bí àwọn ará Sidoni tií máa ṣe. Wọ́n ń gbé pọ̀ ní alaafia, kò sí ìjà láàrin wọn, wọ́n ní ohun gbogbo tí ó wà lórí ilẹ̀ ayé, wọ́n sì ní ọrọ̀. Wọ́n rí i bí wọ́n ti jìnnà sí ibi tí àwọn ará Sidoni wà tó, ati pé wọn kò bá ẹnikẹ́ni da nǹkan pọ̀ ní gbogbo àyíká wọn.
8. Nígbà tí àwọn ọkunrin marun-un náà pada dé ọ̀dọ̀ àwọn eniyan wọn ní Sora ati Eṣitaolu, àwọn eniyan wọn bi wọ́n léèrè pé, “Báwo ni ọ̀hún ti rí?”