20. Ṣùgbọ́n ẹ gbọdọ̀ mú arákùnrin tí ó jẹ́ àbíkẹ́yìn yín wá, kí n ba à le mọ òtítọ́ ohun ti ẹ ń wí, kí ẹ má baà kú.” Wọn sì gbà láti ṣe èyí.
21. Wọ́n ń sọ ọ́ láàrin ara wọn wí pé, “Dájúdájú a ń jìyà nítorí ohun tí a ṣe sí Jósẹ́fù. A rí ìbànújẹ́ ọkàn rẹ̀ nígbà tí ó ń bẹ̀ wá nítorí ẹ̀mí rẹ̀, ṣùgbọ́n a kò gbẹ́bẹ̀, nítorí náà ni ìdààmú yìí fi dé bá wa.”
22. Rúbẹ́nì fèsì pé, “Ǹjẹ́ ń ò wí fún yín pé kí ẹ gbọ́ ẹ̀bẹ̀ ọmọdé-kùnrin náà? Ṣùgbọ́n ẹ kò gbọ́! Nisinsin yìí a ń béèrè ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ lọ́wọ́ wa.”
23. Wọn kò sì mọ̀ pé, Jósẹ́fù ń gbọ́ wọn ní àgbọ́yé nítorí ògbufọ̀ ni ó ń lò tẹ́lẹ̀.
24. Ó yípadà kúrò lọ́dọ̀ wọn, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ní sunkún. Ó sì tún yí padà sí wọn, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ní sọ̀rọ̀. Ó mú Símónì kúrò láàrin wọn, ó sì dè é ní ojú wọn.
25. Jósẹ́fù pàṣẹ pé kí wọn bu ọkà kún inú àpò wọn, kí wọn sì mú owó ẹnìkọ̀ọ̀kan padá sínú àpò rẹ̀, kí wọn sì fún wọn ní ohun tí wọn yóò lò nírín-àjò wọn padá sílé. Lẹ́yìn ìgbà tí a ti ṣe èyí fún wọn,
26. Wọn gbé ẹrù wọn lé kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, wọn sì padà lọ sí ilé.
27. Níbi tí wọ́n ti dúró láti sùn lóru ọjọ́ náà, ọ̀kan nínú wọn tú àpò rẹ̀ láti mú oúnjẹ fún kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀, ó sì rí owó rẹ̀ ní ẹnu àpò rẹ̀.
28. Ó sì wí fún àwọn arákùnrin rẹ̀ pé, “a ti dá owó mi padà, òun nìyí ní ẹnu àpò mi.”Ẹ̀rù bà wọ́n, wọ́n sì ń gbọ̀n, wọ́n sì wí pé, “Èwo nìyí tí Ọlọ́run ṣe sí wa yìí.”
29. Nígbà tí wọ́n padà dé ọ̀dọ̀ Jákọ́bù baba wọn, wọ́n ròyìn gbogbo ohun tí ó sẹlẹ̀ fún-un wí pé,
30. “Ọkùnrin náà tí í ṣe alábojútó ilẹ̀ náà, sọ̀rọ̀ líle sí wa, ó sì fi ẹ̀sùn kàn wá pé a wá yọ́ ilẹ̀ náà wò ni.
31. Ṣùgbọ́n, a wí fun-un pé, ‘Rárá o, olóòtọ́ ènìyàn ni wá, a kì í ṣe ayọ́lẹ̀wò.
32. Arákùnrin méjìlá ni wá, ọmọ bàbá kan náà, ọ̀kan ti kú, èyí tí ó jẹ́ àbíkẹ́yìn wà lọ́dọ̀ baba wa ni ilẹ̀ Kénánì.’
33. “Nígbà náà ni ọkùnrin tí ó jẹ́ alábojútó ilẹ̀ náà wí fún wa pé, ‘Báyìí ni n ó ṣe mọ̀ bóyá olóòótọ́ ènìyàn ni yín; Ẹ fi ọ̀kan nínú àwọn arákùnrin yín sílẹ̀ níbí, pẹ̀lú mi, ẹ sì mú oúnjẹ lọ fún àwọn ará ilé yín tí ebi ń pa kú lọ, lọ́wọ́ ìyàn.