Rom 14:7-18 Yorùbá Bibeli (YCE)

7. Nitori kò si ẹnikan ninu wa ti o wà lãye fun ara rẹ̀, kò si si ẹniti o nkú fun ara rẹ̀.

8. Nitori bi a ba wà lãye, awa wà lãye fun Oluwa; bi a ba si kú, awa kú fun Oluwa: nitorina bi a wà lãye, tabi bi a kú ni, ti Oluwa li awa iṣe.

9. Nitori idi eyi na ni Kristi ṣe kú, ti o si tún yè, ki o le jẹ Oluwa ati okú ati alãye.

10. Ṣugbọn ẽṣe ti iwọ fi nda arakunrin rẹ lẹjọ? tabi ẽsitiṣe ti iwọ fi nkẹgan arakunrin rẹ? gbogbo wa ni yio sá duro niwaju itẹ́ idajọ Kristi.

11. Nitori a ti kọ ọ pe, Oluwa wipe, Bi emi ti wà, gbogbo ẽkún ni yio kunlẹ fun mi, ati gbogbo ahọn ni yio si jẹwọ fun Ọlọrun.

12. Njẹ nitorina, olukuluku wa ni yio jihin ara rẹ̀ fun Ọlọrun.

13. Nitorina ẹ máṣe jẹ ki a tun mã da ara wa lẹjọ mọ́: ṣugbọn ẹ kuku mã ṣe idajọ eyi, ki ẹnikẹni máṣe fi ohun ikọsẹ tabi ohun idugbolu si ọ̀na arakunrin rẹ̀.

14. Mo mọ̀, o si dá mi loju ninu Jesu Oluwa pe, kò si ohun ti o ṣe aimọ́ fun ara rẹ̀: ṣugbọn ẹniti o ba kà ohunkohun si aimọ́, on li o ṣe aimọ́ fun.

15. Ṣugbọn bi inu arakunrin rẹ ba bajẹ nitori onjẹ rẹ, njẹ iwọ kò rìn ninu ifẹ mọ́. Ẹniti Kristi kú fun, máṣe fi onjẹ rẹ pa a kúgbe.

16. Njẹ ẹ máṣe jẹ ki a mã sọ̀rọ ire nyin ni buburu.

17. Nitori ijọba Ọlọrun kì iṣe jijẹ ati mimu; bikoṣe ododo, ati alafia, ati ayọ̀ ninu Ẹmí Mimọ́.

18. Nitori ẹniti o ba nsìn Kristi ninu nkan wọnyi, li o ṣe itẹwọgbà lọdọ Ọlọrun, ti o si ni iyin lọdọ enia.

Rom 14