O. Sol 2:9-14 Yorùbá Bibeli (YCE)

9. Olufẹ mi dabi abo egbin, tabi ọmọ agbọnrin: sa wò o, o duro lẹhin ogiri wa, o yọju loju ferese, o nfi ara rẹ̀ hàn loju ferese ọlọnà.

10. Olufẹ mi sọ̀rọ, o si wi fun mi pe, Dide, olufẹ mi, arẹwà mi kanna, ki o si jade kalọ.

11. Sa wò o, ìgba otutu ti kọja, òjo ti da, o si ti lọ.

12. Awọn itanna eweko farahàn lori ilẹ; akoko ikọrin awọn ẹiyẹ de, a si gbọ ohùn àdaba ni ilẹ wa.

13. Igi ọ̀pọtọ so eso titun, awọn àjara funni ni õrun daradara nipa itanná wọn. Dide, olufẹ mi, arẹwà mi kanna, ki o si jade kalọ.

14. Adaba mi, ti o wà ninu pàlapala okuta, ni ibi ìkọkọ okuta, jẹ ki emi ri oju rẹ, jẹ ki emi gbọ́ ohùn rẹ; nitori didùn ni ohùn rẹ, oju rẹ si li ẹwà.

O. Sol 2