Num 26:40-51 Yorùbá Bibeli (YCE)

40. Awọn ọmọ Bela si ni Ardi ati Naamani: ti Ardi, idile awọn ọmọ Ardi: ati ti Naamani, idile awọn ọmọ Naamani.

41. Wọnyi li awọn ọmọ Benjamini gẹgẹ bi idile wọn: ati awọn ti a kà ninu wọn jẹ́ ẹgba mejilelogun o le ẹgbẹjọ.

42. Wọnyi li awọn ọmọ Dani gẹgẹ bi idile wọn: ti Ṣuhamu, idile awọn ọmọ Ṣuhamu. Wọnyi ni idile Dani gẹgẹ bi idile wọn.

43. Gbogbo idile awọn ọmọ Ṣuhamu, gẹgẹ bi awọn ti a kà ninu wọn, nwọn jẹ́ ẹgba mejilelọgbọ̀n o le irinwo.

44. Ti awọn ọmọ Aṣeri gẹgẹ bi idile wọn: ti Imna, idile awọn ọmọ Imna: ti Iṣfi, idile awọn ọmọ Iṣfi: ti Beria, idile awọn ọmọ Beria.

45. Ti awọn ọmọ Beria: ti Heberi, idile awọn ọmọ Heberi: ti Malkieli, idile awọn ọmọ Malkieli.

46. Orukọ ọmọ Aṣeri obinrin a si ma jẹ́ Sera.

47. Wọnyi ni idile awọn ọmọ Aṣeri gẹgẹ bi awọn ti a kà ninu wọn; nwọn jẹ́ ẹgba mẹrindilọgbọ̀n o le egbeje.

48. Ti awọn ọmọ Naftali gẹgẹ bi idile wọn: ti Jaseeli, idile awọn ọmọ Jaseeli: ti Guni, idile awọn ọmọ Guni:

49. Ti Jeseri, idile awọn ọmọ Jeseri: ti Ṣillemu, idile awọn ọmọ Ṣillemu.

50. Wọnyi ni idile ti Naftali gẹgẹ bi idile wọn: awọn ti a si kà ninu wọn jẹ́ ẹgba mejilelogun o le egbeje.

51. Wọnyi li a kà ninu awọn ọmọ Israeli, ọgbọ̀n ọkẹ, o le ẹgbẹsan o din ãdọrin.

Num 26