Kol 1:25-29 Yorùbá Bibeli (YCE)

25. Eyiti a fi emi ṣe iranṣẹ fun, gẹgẹ bi iṣẹ iriju Ọlọrun ti a fifun mi fun nyin lati mu ọ̀rọ Ọlọrun ṣẹ;

26. Ani ohun ijinlẹ ti o ti farasin lati aiyeraiye ati lati irandiran, ṣugbọn ti a ti fihàn nisisiyi fun awọn enia mimọ́ rẹ̀:

27. Awọn ẹniti Ọlọrun fẹ lati fi ọrọ̀ ohun ijinlẹ yi larin awọn Keferi hàn fun, ti iṣe Kristi ninu nyin, ireti ogo:

28. Ẹniti awa nwasu rẹ̀ ti a nkìlọ fun olukuluku enia, ti a si nkọ́ olukuluku enia ninu ọgbọ́n gbogbo; ki a le mu olukuluku enia wá ni ìwa pipé ninu Kristi Jesu:

29. Eyiti emi nṣe lãlã ti mo si njijakadi fun pẹlu, gẹgẹ bi iṣẹ agbara rẹ̀, ti nfi agbara ṣiṣẹ gidigidi ninu mi.

Kol 1