27. Ti nwọn rò lati mu ki enia mi ki o gbàgbe orukọ mi nipa alá wọn ti nwọn nrọ́, ẹnikini fun ẹnikeji rẹ̀, gẹgẹ bi awọn baba wọn ti gbagbe orukọ mi nitori Baali.
28. Woli na ti o lála, jẹ ki o rọ́ ọ; ati ẹniti o ni ọ̀rọ mi, jẹ ki o fi ododo sọ ọ̀rọ mi. Kini iyangbo ni iṣe ninu ọkà, li Oluwa wi?
29. Ọ̀rọ mi kò ha dabi iná? li Oluwa wi; ati bi òlu irin ti nfọ́ apata tútu?
30. Nitorina sa wò o, emi dojukọ awọn woli, li Oluwa wi, ti o nji ọ̀rọ mi, ẹnikini lati ọwọ ẹnikeji rẹ̀.
31. Sa wò o, emi o dojukọ awọn woli, li Oluwa wi, ti nwọn lò ahọn wọn, ti nwọn nsọ jade pe: O wi.
32. Sa wò o, emi dojukọ awọn ti o nsọ asọtẹlẹ alá èke, li Oluwa wi, ti nwọn si nrọ́ wọn, ti nwọn si mu enia mi ṣìna nipa eke wọn, ati nipa iran wọn: ṣugbọn emi kò rán wọn, emi kò si paṣẹ fun wọn: nitorina, nwọn kì yio ràn awọn enia yi lọwọ rara, li Oluwa wi.
33. Ati nigbati awọn enia yi, tabi woli, tabi alufa, yio bi ọ lere wipe, kini Ọ̀rọ-wuwo Oluwa? nigbana ni iwọ o wi fun wọn Ọ̀rọ-wuwo ni eyi pé: Emi o tì nyin jade, li Oluwa wi.
34. Ati woli, ati alufa, ati awọn enia, ti yio wipe, Ọ̀rọ-wuwo Oluwa, emi o jẹ oluwa rẹ̀ ati ile rẹ̀ ni ìya.
35. Bayi li ẹnyin o wi, ẹnikini fun ẹnikeji, ati ẹnikan fun arakunrin rẹ̀, pe Kini idahùn Oluwa? ati kini ọ̀rọ Oluwa?
36. Ẹ kì o si ranti ọ̀rọ-wuwo Oluwa mọ́, nitori ọ̀rọ olukuluku yio di ẹrù-wuwo fun ontikararẹ̀; nitori ti ẹnyin ti yi ọ̀rọ Ọlọrun alãye dà, Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun wa.
37. Bayi ni iwọ o wi fun woli nì pe: Idahùn wo li Oluwa fi fun ọ? ati pẹlu; Kini Oluwa wi?