Sa wò o, emi dojukọ awọn ti o nsọ asọtẹlẹ alá èke, li Oluwa wi, ti nwọn si nrọ́ wọn, ti nwọn si mu enia mi ṣìna nipa eke wọn, ati nipa iran wọn: ṣugbọn emi kò rán wọn, emi kò si paṣẹ fun wọn: nitorina, nwọn kì yio ràn awọn enia yi lọwọ rara, li Oluwa wi.