Jer 10:7-19 Yorùbá Bibeli (YCE)

7. Tani kì ba bẹ̀ru rẹ, Iwọ Ọba orilẹ-ède? nitori tirẹ ni o jasi; kò si ninu awọn ọlọgbọ́n orilẹ-ède, ati gbogbo ijọba wọn, kò si ẹniti o dabi Iwọ!

8. Ṣugbọn nwọn jumọ ṣe ope ati aṣiwere; ìti igi ni ẹkọ́ ohun asan.

9. Fadaka ti a fi ṣe awo ni a mu lati Tarṣiṣi wá, ati wura lati Upasi wá, iṣẹ oniṣọna, ati lọwọ alagbẹdẹ: alaro ati elese aluko ni aṣọ wọn: iṣẹ ọlọgbọ́n ni gbogbo wọn.

10. Ṣugbọn Oluwa, Ọlọrun otitọ ni, on ni Ọlọrun alãye, ati Ọba aiyeraiye! aiye yio warìri nigbati o ba binu, orilẹ-ède kì yio le duro ni ibinu rẹ̀.

11. Bayi li ẹnyin o wi fun wọn pe: Awọn ọlọrun ti kò da ọrun on aiye, awọn na ni yio ṣegbe loju aiye, ati labẹ ọrun wọnyi.

12. On ti da aiye nipa agbara rẹ̀, on ti pinnu araiye nipa ọgbọ́n rẹ̀, o si nà awọn ọrun nipa oye rẹ̀.

13. Nigbati o ba sán ãrá, ọ̀pọlọpọ omi ni mbẹ loju-ọrun, o si jẹ ki kũku rú soke lati opin aiye; o da mànamana fun òjo, o si mu ẹfũfu jade lati inu iṣura rẹ̀ wá.

14. Aṣiwere ni gbogbo enia nitori oye kò si: oju tì olukuluku alagbẹdẹ niwaju ere rẹ̀, nitori ère didà rẹ̀ eke ni, kò si sí ẹmi ninu rẹ̀.

15. Asan ni nwọn, ati iṣẹ iṣina: nigba ibẹwo wọn nwọn o ṣègbe.

16. Ipin Jakobu kò si dabi wọn nitori on ni iṣe Ẹlẹda ohun gbogbo; Israeli si ni ẹya ijogun rẹ̀: Oluwa awọn ọmọ-ogun li orukọ rẹ̀.

17. Ko ẹrù rẹ kuro ni ilẹ na, Iwọ olugbe ilu ti a dotì.

18. Nitori bayi li Oluwa wi, sa wò o, emi o gbọ̀n awọn olugbe ilẹ na nù lẹ̃kan yi, emi o si pọ́n wọn loju, ki nwọn ki o le ri i.

19. Egbe ni fun mi nitori ipalara mi! ọgbẹ mi pọ̀: ṣugbọn mo wipe, nitõtọ ìya mi ni eyi, emi o si rù u.

Jer 10