Isa 8:1-7 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. PẸLUPẸLU Oluwa wi fun mi pe, Iwọ mu iwe nla kan, ki o si fi kalamu enia kọwe si inu rẹ̀ niti Maher-ṣalal-haṣ-basi.

2. Emi si mu awọn ẹlẹri otitọ sọdọ mi lati ṣe ẹlẹri. Uriah alufa, ati Sekariah ọmọ Jeberekiah.

3. Mo si wọle tọ wolĩ obinrin ni lọ; o si loyun o si bi ọmọkunrin kan. Nigbana ni Oluwa wi fun mi pe, sọ orukọ rẹ̀ ni Maher-ṣalal-haṣ-basi.

4. Nitoripe ki ọmọ na to ni oye ati ke pe, Baba mi, ati iya mi, ọrọ̀ Damasku ati ikogun Samaria ni a o mu kuro niwaju ọba Assiria.

5. Oluwa si tun wi fun mi pe,

6. Niwọn bi enia yi ti kọ̀ omi Ṣiloa ti nṣàn jẹjẹ silẹ, ti nwọn si nyọ̀ ninu Resini ati ọmọ Remaliah.

7. Njẹ nitorina kiyesi i, Oluwa nfà omi odò ti o le, ti o si pọ̀, wá sori wọn, ani ọba Assiria ati gbogbo ogo rẹ̀; yio si wá sori gbogbo ọ̀na odò rẹ̀, yio si gun ori gbogbo bèbe rẹ̀.

Isa 8