1. O si ṣe li ọjọ Ahasi ọmọ Jotamu ọmọ Ussiah, ọba Juda, ti Resini, ọba Siria, ati Peka ọmọ Remaliah, ọba Israeli, gokè lọ si Jerusalemu lati jà a li ogun, ṣugbọn nwọn kò le bori rẹ̀.
2. A si sọ fun ile Dafidi pe, Siria ba Efraimu dìmọlú. Ọkàn rẹ̀ si mì, ati ọkàn awọn enia rẹ̀ bi igi igbo ti imì nipa ẹfũfu.
3. Oluwa si sọ fun Isaiah pe, Jade nisisiyi, lọ ipade Ahasi, iwọ, ati Ṣeaja-ṣubu ọmọ rẹ, ni ipẹkun oju iṣàn ikũdu ti apa oke, li opopo pápa afọṣọ;
4. Si sọ fun u pe, Kiyesara, ki o si gbe jẹ, má bẹ̀ru, bẹ̃ni ki o máṣe jaiya nitori ìru meji igi iná ti nrú ẹ̃fin wọnyi nitori ibinu mimuna Resini pẹlu Siria, ati ti ọmọ Remaliah.
5. Nitori Siria, Efraimu, ati ọmọ Remaliah ti gbìmọ ibi si ọ wipe.